Bibeli ni Ayodeji ati Ayodele ji, l'Adajo ba da ejo iku fun won - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, April 29, 2018

Bibeli ni Ayodeji ati Ayodele ji, l'Adajo ba da ejo iku fun won

Iyalenu loro awon gendekunrin meji ti ile ejo giga tipinle Ekiti da ejo iku fun pe ki won loo ye igi fun won titi temi yoo fi jabo lara won si n je fawon to gbo nipa isele naa.

Ariyo Ayodeji, eni odun mejilelogun ati ore e, Ayodele Oluwakayode, eni ogun odun ni adajo, Lekan Somoye ju sewon leyin ti won jebi esun idigunjale ti won fi kan won pe won fipa gba bibeli, iwe orin ati opolopo owo lowo Arabinrin kan, Stella Faniyi.

Gege b'AWIKONKO se gbo, ninu esun ti won fi kan won loju iwe 516 ati 402(2) ti iwe odaran ipinle naa, won ni ojo kinni in osu keta odun 2016 ni loo ja Stella lole ni Plot 18, adugbo Oke-Osun, Ikere-Ekiti, ti won si fibon gba baagi lowo e.

Ninu baagi naa la gbo pe awon nnkan bii foonu olowo nla Nokia Lumia, foonu ti ileese Airtel, ATM, bibeli, iwe orin ati owo lo wa ninu e. Asiko ti Stella n bo lati soosi la gbo pe won fi okada tele, ti won si fibon gba baagi e.

Lesekese ni Stella ti gba tesan olopaa to wa ni Ikere lo lati loo foro naa to won leti, tawon yen naa si bere ise iwadii won.

AWIKONKO tun gbo pe ni nnkan bi aago mejo ale ojo kejidinlogun osu keta odun 2016 naa lawon odaran yi tun loo fibon ja Arabinrin Bunmi Arije lole ni 11 Avenue Federal Housing Estate opopona Afao Road, Ado-Ekiti.

Lara awon nnkan ta a gbo pe won gba lowo e ni foonu Samsung ati BlackBerry, ATM, kokoro, kaadi awako (driver's license) ati egberun mesan an (9,000) naira.

Nigba towo palaba won maa segi, asiko tawon olopaa n ye awon moto wo kaakiri ipinle naa ni won ko si won lowo, ti won si bere sii ka boroboro.

Ileejo Majisireeti ti Ado-Ekiti la gbo pe won koko gbe won lo, ko too di pe ajo DPP gbawon nimoran pe ki won gbe won lo sile ejo giga, bo tile je pe ojo kerindinlogun osu keji odun 2017 ni won koko foju won bale ejo, latigba naa lawon olopaa ti bere sii topinpin won lati ri eri aridaju.

Bo tile je pe awon mejeeji so pe awon ko jebi pelu awon esun ti won fi kan won, sibe adajo ile ejo naa, Ogunmoye pase pe ki won loo sewon odun marun-marun un, bee ni ki won tun yegi fun won pelu esun idigunjale.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI