Won sa Big Sam, ogbologbo omo egbe okunkun pa l’Osiele - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 18, 2018

Won sa Big Sam, ogbologbo omo egbe okunkun pa l’Osiele

Titi di bi e ti n ka iroyin yi lokan awon olugbe ilu Osiele nijoba ibile Odeda, Abeokuta ipinle Ogun ko tii fi bale, latari bi won se sa Big Sam to je okan lara awon omo egbe okunkun pa mole.

Oku Big Sam
Ni nnkan bi aago mokanle ale ojo Tosde la gbo pe won loo ka Big Sam mo ile okan lara awon omo ile eko giga tawon olukoni, iyen FCE ti won ni Big Sam n fe, ti won si sa a bi eran ileya, titi temi fi jabo lara e.

Bo tile je pe ko seni to fe e soro nipa bi won se pa Big Sam nitori to je gbajumo ninu egbe okunkun ti aye, ti won si lawon omo egbe okunkun egbe e n wa eni ti won yoo fi se eran ewure bi won ba fi le maa gbe iroyin naa kaakiri.

A gbo pe okunrin kan lo wa odomobinrin akekoo FCE ti Big Sam n yan ni ale wa sile, ti won si ni asiko naa gan an ni Big Sam de, sugbon won nib o se ri won, ibinu lo fi wonu ile.

Iyalenu lo je pe bi Big Sam ti won loo ti bimo okunrin kan, ati pe iyawo e to fe sile n ta worobo ninu ileewe ekose tijoba, iyen Government Technical College, Idi Aba, Abeokuta, se lawon meta kan tele e wole, ti won si bere sii luu.

Agidi ta a gbo pe Big Sam bawon se lo je ki won gbe e jade seyinkule ile naa ti won leyin soosi The Apostolic tawon akekoo n lo wa, nibe ni won sis a a pa sii, tawon yen si salo.

Lesekese la gbo pe awon araadugbo ti ranse pea won olopaa lati fi to won leti, ti won lawon olopaa si ti bere ise iwadii lati mo awon to wa nidii ise naa, ati pe won lawon SARS ko je kawon eeyan gbadun ninu ilu naa, nitori ti won so pe ojoojumo ni won n le awon eeyan kaakiri bi aago meje irole ba ti lu.

Big Sam
Lati fidi isele naa mule, AWIKONKO gbiyanju lati ba Asaaju Aje ati Jagunmolu ilu Osiele naa soro lori foonu, tawon mejeeji si so pe looto ni, ati pe olopaa atawon soja ti n kaakiri ilu naa latigba tisele naa ti sele.

Bee ni won rawo ebe sijoba lati gbawon lowo awon omo egbe okunkun to n dawon laamu ninu ilu naa, won ni ojoojumo ni won n po si, ati pe ileewe FCE ni Big Sam ti kekoo jade, sugbon inu egbe buruku to wa ni ko je ko ti fagbegbe naa sile.

Oloye John Adio Oyeleye to je Jagunna ilu Osiele nigba to n so kulekule isele naa f’AWIKONKO lojo Fraide ose to koja yii, o ni awon ko seni to mo pe isele to sele lojo Monde ose to lohun, iyen ojo keji osu yi maa di osu ata yannyan an nitori to so pe awon kan ti won ko tii mo titi dasiko yi ti yinbon fun odomokunrin kan nibi ti won ti n se faaji, to je pe awon eeyan ni won sare gbe e lo si osibitu lati doola emi e.

Jagunna naa so pe oro eni ti won yinbon fun lawon si n fa lowo ko too di pe won tun loo ka Big Sam mole, ti won si sa a pa, eyi gan an lo ko iberubojo bawon araalu, to fi mo awon oloye.

Baba agbalagba naa tun je ko di mimo pe ki wahala naa ma baa tun po ju oju tawon fi n wo lo, lo je kawon ranse sawon agbofinro bii olopaa, soja, sifu difensi ati Fijilante lati wa daabo bo won nitori pe.awon kan tun n ko ara won jo lati da wahala sile.

Gbogbo igbiyanju lati ba Abimbola Oyeyemi to je agbenuso fawon olopaa soro lo ja si pabo, nitori ti ko gbe foonu lati ko ta a pe, ti ko si tii da esi atejise pada titi dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI