Nitori owu: Yemi gun afesona e pa l'Owode Ijako - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, April 18, 2018

Nitori owu: Yemi gun afesona e pa l'Owode Ijako

Titi di bi e ti n ka iroyin yi loro odomokunrin kan ti won pe oruko e ni Yemi Isa to seku pa iyawo afesona e,  lojo Satide to lo lohun si n je fawon araadugbo, paapaa awon to gbo sisele naa.

Yemi Isa
Ni nnkan bi aago meji aabo oru ojo Satide mojumo Sande la gbo pe Yemi loo ba Oluwakemi eni odun marundinlogbon (25) ninu yara to n sun ni ojule keje adugbo Alade Road, Owode/Ijako, ijoba ibile Obafemi/Owode, ipinle Ogun, to si loo gun un pa mo'be.

Gege bi awon to fisele naa to AWIKONKO lowo se so, won ni asiko ti gbogbo awon to n gbe ninu ile koju-simi-ki-n-koju-si-o olojule mejo naa ti loo sun ni Yemi ri aaye ja ilekun wole lati eyinkule, to si gba yara ti Oluwakemi sun lo lai je ki enikeni mo.

Ohun ta a gbo ni pe o ti le lodun meji ti Yemi ati iyawo afesona e, Oluwakemi Ilo ti jo n ba ere ife won bo, sugbon sadede la gbo pe nkan yi pada ti won ni Yemi bere sii jowu ainidi, to si n maa n da wahala sile laarin awon mejeeji.

AWIKONKO gbo pe opo igba ni Yemi ti lu Oluwakemi lalubami, ti ko si nii so fenikeni, nitori ti won so pe Oluwakemi dinu funra e, kii ba a yan soro, paapaa oro to ba n dun un.

Bo tile je pe ko seni to tete mo pe Yemi lo sise naa, sugbon ileri iku ta a gbo pe o ti se fun Oluwakemi ati iya e, Arabinrin Tawakalitu Ilo lo mu ifura dani, ti won si ni ko seni meji to le sise naa, bi ko se oun.

Oluwakemi
A gbo pe nigba ti won fura sii lo je kawon odo adugbo naa gba ile ti Yemi n gbe lodo ore e to wa ladugbo naa lo, sugbon nigba ti won maa de be, ibi to ti n palemo aso e lati na papa bora ni won ti ba a.

Won ni seni Yemi ti won ni ko nise lapa, sugbon ise soja lo fi n boju, to si tun ni kaadi ologun orisi marun un lowo, iyen kaadi idanimo Navy, Sifu Difensi, Army, Legion ati Man O War.

A gbo pe agbegbe Iyana Ilogbo ni Yemi maa n duro si pelu awon soja kan, ti won maa n fipa gbowo lowo awon araalu atawon olokada pelu onimoto, bo tile je pe a gbo pe awon soja naa ko mo pe Yemi kii se ojulowo omo egbe ologun.

Won ni ninu osu keji odun yi ni Oluwakemi ti so pe oun ko le fe Yemi mo, ki onikaluku maa lo lotooto, eyi la gbo pe o fa a, ti Yemi fi bere sii leri sii pe oun ko nii je ko ri ojuraye gbe ile aye nitori to ti mo gbogbo asiri ikoko toun ti so fun.

Ohun ta a tun gbo ni pe gbogbo Foto Yemi atawon atejise idunkoko ti Yemi fi ranse sori foonu Oluwakemi lo sare pare lasiko naa ki asiri e ma baa tu sita, nitori ta a gbo pe opo awon eeyan lo ri atejise naa lojo Satide kisele naa to sele, sugbon bawon atejise atawon Foto naa se kuro lori foonu lo tun je ki won mo pe Yemi lo wa nidi isele naa. 

Iya Kemi
Nigba yo n fomije b'AWIKONKO soro ninu ile naa lojo Monde ose to koja yi, iya Oluwakemi, Arabinrin Tawakalitu to loun ti le lodun marundinlaadota (45) so pe kijoba gba oun,kinwon ma je ki Yemi fiya je oun gbe nitori pe omo kan soso toun gbojule ninu awon omo toun bi ni oko afesona ti pa moun lowo.

Ninu oro Tawakalitu to ni ounje loun n ta lo ti so pe, "Ni ijerin, ojo Fraide, mo pe Kemi omo mi, nomba e ko lo. Igba to de pada, mo bere sii ba wi pe ki lo de ti mo n pe nomba e ti ko gbe. O wa so pe Yemi ti wa gba foonu lowo oun. O ni so pe awon to maa n wa jeun ma n jokoo ti won ba jeun tan, ati pe tani won maa n jokoo ti. Kemi loun so fun pe awon onibara momi oun ni.

"Ibe lo ni o ti bere sii sepe foun pe oun maa to ri isoro lai pe, oro yen lo wa ta mi lara ti mo fi pe lori aago. Kemi kii fe e ki n mo toun ati Yemi ba ti n ja, nitori o mo pe mo maa ba a soro. Mo wa pe Yemi, mo kilo fun pe ko ma fi omo mi sepe mo, se lo gba sodi, to si bere sii bu mi.

"Ko pe lo tun wa ba mi, to bere sii soro si mi pe emi ko fe ki Kemi fe oun, o sa n bu mi, sugbon mi o soro. O tun ni omo mi maa gba, oun a ko lekoo. Iru nkan bee ti sele ri to je pe enikan ti wa a fi bileedi ya omo mi lara laarin oru, to je pe se la sare gbe e lo si osibitu ni nkan bi aago meta oru, mi o tete fura sii, sugbon eleyi to se lonje ki n mo pe oun lo sise yen ninu osu keji odun yi.

"Ojo kan ni mo ye foonu Kemi wo, ti mo si ri orisirisi bi Yemi se n sepe fun, pelu awon atejise idunkoko, mo beere lowo omo mi, sugbon o ni ki n maa wo ni temi. 

"Ni nnkan bi aago meta oru ni eni ti Kemi sun ninu yara e to je omoomo onile wa ranse pe mi pe ki n maa bo, won tun ti sa Kemi lori. Igba ti mo maa debe inu agbara eje ni mo ti ba ti won fi aso dii lenu. Mo beere pe bawo lo se sele, won lawon ko mo bi eni naa se wole, pe awon kan n gbo ti eeyan n gbin, igba tawon de be lawon ri Kemi.

Oku Kemi
"Nibe la ti bere sii gbe lo si osibitu ko too di pe o dake loju ona. Lesekese ni mo je kawon eeyan mo pe Yemi lo sise naa. Igba ti won lo wo nile iya e, iya e so pe o sese kuro ni, won tun lo wo nile ore e to n gbe, ibe ni won ti ba nibi to ti n ko eru si baagi, won lo so pe oun fe lo fo aso ni. O ti wa ni tesan olopaa bayii."

Bo tile je pe awon olopaa ti won wa a gbe oku Oluwakemi lo si mosuari lojo Monde naa so pe awon ko le ba wa soro, ayafi alukoro won, sugbon oun ta a gbo ni pe won ti gbe Yemi lo si olu ileese olopaa to wa ni Eleweran niluu Abeokuta.

Lati fidi isele naa mule, Agbenuso fawon olopaa, Abimbola Oyeyemi so pe oun ko tii gbo nipa isele naa, ati pe oun yoo je ka gbo leyin toun ba se iwadii lori e, ti ko si tii je ka mo bo se n lo titi ta a fi sakojopo iroyin yi tan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI