“E
se wa jeje, ise esu ni” loro ebe to n jade lenu gendenkunrin meji tojo ori won
ko tii ju odun mokandinlogun lo, ti won fesun kan pe won fipa bomodun merinla
kan ta a foruko bo lasiri lo po lagbegbe Obantoko niluu Abeokuta.
Ojo
Abameta Satide to koja lo lohun la gbo pe Abiodun Ishola, eni odun mejidinlogun
(18) ati ore e, Kehinde Oloyede, eni odun mokandinlogun (19) fogbon tan
omodebinrin naa ti won nise aserunloge (hairdresser) lo n ko.
AWIKONKO gbo pe laaro kutu ojo naa nigba ti omo naa n lo sibi ise to n ko ni
Abiodun pe e pe eto gbale-gbata wa nita, ati pe eni ti won ba mu, ijoba maa
muu, to si ni ko wa a jokoo sodo oun, bo se jokoo lo tun ba a gbe baagi e wo yara lo, lai mo pe nnkan to fe e se wa lokan e.
Nigba
ti eto gbale-gbata naa pari, ti omo naa fe maa lo sile, ni Abiodun so
fun un pe ko wole loo gbe baagi e, bo si se wole lo ba tele pelu ore e,
Kehinde, ti won si n fipa bo aso e.
Ariwo
ta a gbo pe omo naa n pa sita lo je kawon to wa nitosi sare loo wo
nnkan to n sele, ki won si too de be, Kehinde ti fese fe e, ti won si ba
Abiodun nibi to ti n ko ibasun fun un karakara.
Bi won se kaa mo ni won ti bere sii luu, to si je ki won mo pe oun nikan ko loun se e, to si mu won lo sile Kehinde.
Nibi
ti won ti n lu Abiodun ati Kehinde lawon eeyan ti so pe ki won loo fa
won le awon olopaa lowo, ti won si gbe e lo si tesan olopaa to wa ni
Obantoko nibi ti won gba de Eleweran.
Agbenuso
fawon olopaa, Abimbola Oyeyemi jeri sii pe looto ni, ati pe oga won,
Ahmed Iliyasu ti tare awon ore mejeeji si eka ileese olopaa Anti Human
Trafficking and Child Labour Unit nibi ti won ti n foro wa won lenu wo.
No comments:
Post a Comment