Nitori oyun: Omodun metadinlogun gbemi ara e - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 8, 2018

Nitori oyun: Omodun metadinlogun gbemi ara e


Iyalenu loro omodebinrin omodun metadinlogun (17) kan ti won poruko e ni Abibatu si n je fawon ara adugbo Apamini lagbegbe Rumuokoro nijoba ibile Obio/Akpo, ipinle Rivers si n je lori bo se lo o mu oogun apefon.
Gege bi eni to gbe iroyin naa s’AWIKONKO leti lose to koja yi se so, won ni se ni Abibatu ti won nile eko girama lo si wa loo gbe oyun ka awon obi e mole, tawon yen si fibinu ba a wi pe ko mu awon lo sodo eni to fun un loyun, iyen lojo Fraide to lo lohun.
Eni naa je ko ye wa pe nigba ti Abibatu ko jewo fun won, ni won so fun un pe se lawon yoo le danu, tawon ko sin ii ran lo sile eko mo. Oro yi la gbo pe o bi Abibatu ninu, to loo fibinu ra oogun apefon ni soobu kan to wa nitosi ile won.
Nigba ti won maa pada rii ni ale ojo naa, oku e ni won ba, ta a si gbo pe bi won se gboorun enu e, ni won rii pe oogun apefun lo mu, tiyen si je gbogbo ifun e, to si gba be soda sorun alakeji.
Titi di bi e ti n ka iroyin yi la gbo pe won ko tii mo eni to fun Abibatu loyun naa, ti won si so pe inu ibanuje nla lawon obi e wa, ti won n kabamo oro ti won so sii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI