ADEBUTU FUN MAYUNGBE, ODEMO TI ISARA REMO NI MILIONU MEWAA NAIRA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 25, 2018

ADEBUTU FUN MAYUNGBE, ODEMO TI ISARA REMO NI MILIONU MEWAA NAIRA

Titi di bi e ti n ka iroyin lawon omo bibi ilu Isara Remo si fi wa ninu idunnu ati ayo lori bi Oba Albert Adebose Mayungbe se gba opa ase gege bi Odemo tiluu Isara Remo, ipinle Ogun.


Ojo Tosde to koja yi la gbo pe Komisana foro oye jije nipinle Ogun, Omoba Babajide Ojuko gbe opa ase fun Oba Mayungbe niluu Isara leyin odun mokanla ta a gbo pe won ti yan Kabiyesi naa.

Lara awon ti won wa nibi ayeye igbade naa ni Onorebu Ladi Adebutu tawon eeyan mo si LADO ti Onorebu Adebiyi Adeleye topo eeyan mo si Jagaban soju e.

Bo tile je pe AWIKONKO ko si nibi eto ayeye igbade naa, sibe awon to fi nnkan to sele nibi ayeye ti gbajumo sorosoro nni, Olumide Awolowo edari eto, to wa leti je ko ye wa, Onorebu Adebutu fi ero amunawa, iyen jenereto ta Oba tuntun naa lore pelu milionu mewaa naira.

Onorebu Adeleye nigba to n gba enu Onorebu Adebutu soro so pe ipo Odemo tiluu Remo je ipo Oba lori gbogbo egbe oselu niluu naa, eyi gan an lo fa a ti Adebutu se fi awon ebun naa da a lola.

Awon min in ti won tun wa nibi ayeye naa ni Baba Toyese Adekoya, Amsterdam ati
Adeomoade ti won tuko eto pelu Awolowo tawon eeyan tun n pe ni Gedu-Master.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI