NITORI OBASANJO, GNI FI EGBE OSELU PDP SILE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 25, 2018

NITORI OBASANJO, GNI FI EGBE OSELU PDP SILE

Bo tile je pe kii se akoko re e ti adije sipo gomina ipinle Ogun lodun 2011 ati 2015, Omoba Gboyega Nasiru Isiaka yoo fi egbe oselu PDP sile lati di gomina ipinle naa, sugbon eyi to n je iyalenu fawon eeyan ni bi won se fe e mo inu egbe oselu to fe e gba jade lati dupo kan soso naa lodun 2019.

Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo laaro onii, ojo Tosde to koja yi ni won ni Omoba Gboyega Nasiru Isiaka to n wa gbogbo ona lati di gomina ipinle Ogun ninu eto idibo to n bo lona fi egbe oselu PDP sile lati ronu egbe oselu min in ti yoo gba jade.

Ninu leta naa ti GNI ko si alaga egbe oselu PDP naa, o je ko di mi mo pe kii se pe oun deede fi egbe naa sile, nitori kii se nnkan to rorun lati fi egbe naa sile lakoko yii, sugbon toun ko tun gbodo ma tete kuro nibe latari wahala ojoojumo tegbe naa n koju, tawon adari ko si wa nnkan se sii.

O ni ipalara to po ati akoba nla ni yoo je foun boun ko ba tete fi egbe naa sile lati wa egbe oselu min in se.

Fawon to ba mo ipo ti egbe oselu PDP wa nipinle Ogun, won yoo mo pe egbe naa ti pin si meji, eyi tawon kan fara mo Seneto Buruji Kashamu to n soju ekun Ogun East nile igbimo asofin agba niluu Abuja, tawon min in si wa lodo Onorebu Ladi Adebutu toun n soju ekun Remo nile igbimo asofin kekere niluu Abuja.

Nigba to n b'akoriyin ileese Ogun Today soro lati mo egbe oselu ti GNI fe e gba jade lati dupo gomina lodun 2019, Ogbeni Wale Junaid to je amugbalegbe Isiaka leka iroyin so pe ko tii to asiko lati je kawon araalu mo egbe ti oga oun fe e gba jade, nitori pe abewo sawon agbaagba leka eto oselu si n lo lowo.

Ninu iwadii ti AWIKONKO se la ti mo pe egbe oselu ADC ti Obasanjo sese da sile ni GNI ni lokan lati gba jade, nitori to gbagbo lero okan e pe eni ti baba naa, to tun je Aare tele ri lorileede yi ba ti fa sile lawon araalu yoo tele.

Ohun kan to tun n kan awon eeyan lominu, ti ko tii ye awon eeyan ni bawon kan se ro pe egbe oselu APC ni okunrin omo bibi Yewa naa fe e gba jade, ti won ti ro pe oun ni Gomina Amosun fe e fa kale, sugbon tawon kan so pe Baba Obasanjo to n tele lasiko, to si tun ti di iranse e lo se pinu lati tete fegbe oselu PDP sile, ko le je pe oun ni won yoo fa kale legbe oselu ADC ti won sese da sile.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI