Anfaani nla fe e wo ilu Ibadan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 15, 2018

Anfaani nla fe e wo ilu Ibadan


Ibeere tawon akopa, paapaa awon to wa lati ona to jin in nibi idanilekoo olojo-kan tileese Business Executive International pelu ajosepo Business Development and Support Services gbe kale fawon araalu sagbateru e niluu Abeokuta, ipinle Ogun lojo Abameta Satide, ojo kokanlelogun osu kerin (April 21) odun yi ni pe igba wo ni fe e gbe iru idanilekoo be e wa si odo awon.

Ko si nnkan meji to mu ki won maa beere ibeere naa ni bi won se so pe oju awon la sawon anfaani to wa lagbegbe ati ayika won, eyi ti yoo maa mu owo repete wole fun won yato si ise tonikaluku won yan laayo, paapaa awon osise feyinti.

Idanilekoo naa tawon akopa to wa lati ona to jin in bii ipinle Eko, Oyo, Osun atawon min in tii kopa lawon eeyan si n kan saara si pe awon ko fi owo moto awon s’ofo pelu anfaani tawon ri je nibi idanilekoo naa, bo tile je pe won ko san owo iwole.

Leyin idanilekoo naa, lesekese lawon eeyan ti won ko gbe niluu Abeokuta ti n bebe pe ki won ba won gbe idanilekoo naa wa siluu awon, iyen awon ilu bii Ibadan, Eko, Ogbomoso, Osun ati beebeelo, kawon ti won ko tii gbo nipa e naa le je iru anfaani tawon je.

Ni bayii, ohun ta a gbo ni pe ojo Abameta Satide to n bo yii, iyen ojo kokandinlogun osu yi ni ileese Business Executive International to wa niluu Abeokuta pelu ajosepo ileese Tunkas Business Enterprises to wa ni Apata niluu Ibadan tun gbe idanilekoo olojo-kan min in sile fawon olugbe ilu Ibadan lori awon ona ti won yoo gba lati maa fi ri owo.

Gege bi atejise ti awon adari ileese naa gbe jade sita, eyi ti eda e te AWIKONKO lowo laaro onii, won je ko di mi mo pe ko si idi meji pataki ti won fi n gbe idanilekoo naa kaakiri orileede Naijiria, paapaa ile Yoruba bi ko se bi eto oro aje orileede yi se n denu kole, tawon eeyan si n wa ona abayo lori ona ti won yoo gba lati maa fi ri owo.

Won je ko ye wa opo awon eeyan lo letoo lati je anfaani naa, yala onise owo, olokoowo, osise ijoba, osise ileese aladani, osise feyinti, to fi mo awon to n gbaradi lati feyinti lenu ise won.

AWIKONKO gbo pe inu gbongan oja igbalode kan ti won pe ni Kabiyesi Shopping Complex, legbe ileewe girama Adifase (Adifase High School), Ahmadiya, Apata niluu Ibadan ni idanilekoo naa ti fe e waye fawon olugbe ilu Ibadan jake-jado laago mewaa aaro.

Yato si awon osise ijoba atawon onise aladani, pelu awon onisowo kekeeke, awon bii awako, mekaniiki, olokada, asaraloge, aserunloso (hairdresser), telo (tailor), weda (welder) ati bee bee lo ni won n reti nibi idanilekoo naa lati wa a je anfaani.

Ogbeni Kolawole Adejojo to je agbenuso fawon ileese naa nigba to tun b’AWIKONKO soro, so pe ofe ni owo iwole, ko si wi pe won n gba owo foomu, sugbon nnkan kan soso tawon to fe e kopa nibi idanilekoo naa gbodo mu dani ni takada ati kalaamu (iwe ati bairo).

Bakan naa lo tun so pe orisirisi ona eru lawon eeyan, paapaa awon odo asiko yi n wa lati fi ri owo, sugbon bi won ba kopa nibi idanilekoo olojo-kan soso yi, igbagbo ati idaniloju wa pe won yoo rerin ayo nigba ti aye won ba yi pada nibi idanilekoo naa.

Fun alaye lekunrere, tabi lati to o yin s’ona, e le kan si awon nomba yi 07065407593, 08138426960

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI