Oju mi ko riran daadaa mo - Pa Kasumu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, May 14, 2018

Oju mi ko riran daadaa mo - Pa Kasumu


Ko seni to gbo bi gbajumo osere tiata ni, Ogbeni Kayode Odumosu topo awon ololufe e mo si Pa Kasumu se n soro lai pe yi, nile to n gbe ni Mowe-Ibafo, ipinle Ogun lose to koja yi, ti aanu ko nii se e, paapaa nigba to tun so pe ko seni to ranti oun mo laarin awon ti won jo n sise tiata kaakiri orileede Naijiria, paapaa loke-okun.

Pa Kasumu to lodun 1973 loun bere ise tiata nigba to n b’AWIKONKO soro, to tun fe e le maa yo omi loju so pe oun si nilo iranlowo owo fun aisan oju to n ba oun finra, bo tile je pe omo oun ko nife sii pe koun maa toro owo lowo awon eeyan, sibe, ko si nnkan toun tun le se ju koun rawo ebe sawon omo Naijiria lati ma je koun ku lasiko yi. E ka bi iforowero naa se lo.

AWIKONKO: Oruko yin lekunrere ati bi e se bere ise tiata?
PA KASUMU: Oruko mi ni Olukayode Olugbenga Odumosu. O ti le logota odun ti won ti bi mi. omo bibi ipinle Ogun ni mi. Baba mi wa lati ilu Odogbolu nigba ti Mama mi je omo Egba niluu Abeokuta. Mo saba maa n pe ara mi Ijegba (Ijebu-Egba). Odun 1973 ni mo bere ise tiata ni kikun. Nigba yen, mo je okan lara awon osise ileese awako kan niluu Eko. Iporin ni mo n gbe. Nigba ti n ba n bo lati ibise, mo maa n ri awon eeyan ti won n se ere ori itage.

Mo so si okan mi pe oye ki emi naa le darapo mo won, ki n si se daadaa pelu ise yen. Mo loo ba adari egbe yen lati so erongba mi, lesekese lo gba mi. Bi mo se fi ise ti mo n se sile niyen ti mo si bere pelu won. Nigba ti mo bere, o dun mo mi gan an, mi o ri gege bi nnkan babara tabi nnkan to le. Mo nilo owo nigba yen, eyi lo je ki n fi ise ti mo n se tele sile, ki e si maa wo o, nigba yen, owo gidi wa ninu ise tiata nigba yen.

AWIKONKO: Nje ise tiata ti e ko ipa to joju nigbesi aye yin, ati pe inu egbe osere wo leyin wa?
PA KASUMU: Beeni, ise tiata se pupo ninu igbesi aye mi gan an. O je ki oju mi la sawon nnkan to sokunkun, o tun je ki n gbon ju bi mo se lero lo. E je ki n jewo fun un yin, mo ko eko pupo lara awon ta a jo n sise tiata. Igbe aye won yato si ara won, bee naa ni ihuwasi won ko jo ara won rara. Mo ti bawon se egbe ANTP. Mi o lero pe egbe naa si tun wa mo. Egbere osere TAMPAN ni mo tun n gbo bayii, awon osere Yoruba nikan lo si wa fun.

Okunrin kan ti won n pe ni Afolabi lo ko mi nise tiata. Oun lo ni Simbad Concert. Olorun Egbon lo ko Afolabi nise. Mo kopa ninu orisirisi ere ori itage ati sinima repete bii Wole-Wole, Arufin, Iyawo Orun. Iyawo Orun yi gan an lo gbe mi si aye, oun lo je ki n di ilumon on ka. Nigba ti won maa se fiimu yen, won n wa enikan ti won le lo lati ko ipa kan, mo ni lati fi ara mi sile pe mo le se e, won si yan mi. Mo se daadaa, inu oga mi si dun debi pe, o patewo fun mi, o tun bo mi lowo. Nnkan iyi gidi ni nigba yen.

AWIKONKO: Ki lo fa aisokan ati eleyemeya laarin awon osere tiata lorileede Naijiria?
PA KASUMU: Awon osere tiata soro lati ko won papo jo soju kan naa. Boya le mo pe latigba ti mo ti wa nibi (Mowe) yi latari aisan ti mo ni, ko si eyikeyi ninu awon osere tiata to ti yoju si mi lati wa se abewo si mi. Ko da nigba ti mo si wa niluu Abeokuta, mi o ri enikeni, bo tile je pe pupo ninu won lo n gbe Abeokuta. Aisokan to wa laarin won lo da eyi sile. O see se ko je pe ilara lo fa oro aisokan yi, Olorun nikan lo ye. E wo Olumide Bakare. E wo opolopo ojo to lo ni osibitu ko to o ku, mi o lero wi pe a ri enikan ninu awon onise tiata to lo o yoju sii. Bo tile je pe asiko yen gan an ni aisan ara mi le gidi, sibe mo si tun n gbiyanju lati rii pe a n soro latigbadegba daadaa.

Oro ti Pasito Ajidara naa je nnkan to ba mi ninu je d’okan, to si dun mi wonu egungun gidi. To ba je pe se la wa papo, o see se ko je pe nnkan to dojuko le ma pada seku pa a. E wo emi naa bayii, awon elegbe mi ti pa mi ti, o je nnkan to buru jai, sugbon mo dupe pea won ebi mi ko pa mi ti. Mi o le gbagbe awon to ti ku bii Olumide Bakare ati Pasito Ajidara.

AWIKONKO: Ki ni pataki aisan to n se yin?
PA KASUMU: Aisan to n se mi nii se pelu oju mi, mi o riran daadaa bii ti tele mo. Nnkan maa n di pupo loju mi ni. Bi e se duro ti e n ba mi soro yi, se lo dabii pee yin meji le duro niwaju mi. Mo fe e dupe lowo omo mi. o duro ti mi pelu orisirisi adojuko ati ipenija, to n mu mi lo lati-ibikan si ibomin in. mo ti lo s’ibi kan ti won ti n se oju n’Ikoyi. Mo ti lo si India fun itoju. Odun mesan seyin ni wahala yi bere, iyen lojo kesan an osu kejila odun 2009.

Nigba to bere, omo mi nikan lo duro ti mi, o je omo to ni irele. Mo n san egberun merinlelogbon (34,000) naira si egberun merindinlogoji (36,000) naira lose-ose fun itoju. Nigba yen, mo si ni awon owo kan ninu apo ile ifowopamo (Bank Account) mi, mo ri awon owo yen pelu bi mo se gba’le-gba’ta. O ye ki n na owo yen, sugbon mo fe e fi owo naa kan paanu ile mi ti mo n ko si agbegbe Ogijo ni, owo naa to milionu merin (#4) naira. Sugbon nigba ti aisan yi de, gbogbo owo yen lo lo si patapata.

AWIKONKO: Se ka so pe ajalu to wonu egbe osere lowo aye ninu ni, nitori pe a gbo ti Moji Olaiya, Olumide Bakare, Pasito Ajidara atawon min in bee na?
PA KASUMU: Kii se awa osere nikan. Gbogbo eeyan kaakiri-kaakiri ni. Mi o ri gege bi ise aye, nitori pea won osere kan naa si wa, ti won ko gbajumo, tawon naa ti ku latari aisan to kolu won. Ni temi, mo si n dupe lowo Olorun nitori pe lati bii odun mesan an seyin, bi Olorun ko ba si ni emi mii lo, ko nii da mi si titi dasiko yi.

AWIKONKO: Ni bayii, e o se sise tiata mo. Nje a le ri eeyan ti yoo tun maa ko awon ipa ti e ko tele, abi majiiki kan wa ninu aseyori yin?
PA KASUMU: Ni temi o, Olorun ni. Bi a ba n so nipa boya a tun le ri eni ti yoo sebi temi nidi ise tiata. O le gba opolopo asiko, sugbon sibe, enikan, nibikan si maa gba ipo yen, teni naa si maa se e daadaa. E gbo o, mi o tii ku bayii. Mo si ni afojusun. Mo si ni ireti pe mo si maa fi ese mi mejeeji rin. Mo si maa pada sidi ise tiata bi ara mi ba ti ya.

Ko si nnkan to se ese mi, bo tile je pe mi o le rin daadaa, die-die ni mo n rin, sugbon, sugbon mo nigbagbo pe Olorun oluwosan yoo gbakoso. Bi e ba n wa eni ti yoo wo bata ti mo ba bo sile nidi ise tiata, o le gba asiko. Mi o mo. Sugbon ti e ba n so pe ko seni to tun le wo bata yen, e je ki n so fun un yin pe a ni awon osere ti won le se e. Bi ile aye se wa niyen. Ko si nnkan to je babara ninu ipa ti mo n ko.

AWIKONKO: Bi eelo le nilo bayii lati toju ara yin ati pe awon wo lo ti ran yin lowo tele?
PA KASUMU: Mo so fun un yin tele pe mo ti lo si India. Won gbiyanju agbara won. To ba je pe mo ri anfaani lati tun pada lo leekeji to ye ki n pada lo ni, o see se ki nnkan ti yi pada si daadaa. Mi o le pada lo nigba yen nitori pe mi o ri owo lati lo. Milionu meji ataabo (#2.5) naira ni owo ti mo koko fi lo, sugbon eleekeji to ye ki n pada lo, milionu meji din legberun lona igba (#1.8) naira ni mo nilo, sugbon ti mi o pada ri ko jo. Owo yen le ti tun han si pelu eto oro aje wa. Inu mi i ba dun ti n ba tun ri anfaani lati pada lo. Sugbon nnkan to n kan mi lominu ni pe se ni won tun sese maa bere itoju mi lat’ibere.

Owo ti mo maa nilo bayii ko le ju milionu meji (#2) naira lo, lati ra oogun. Awon oogun ti mo n lo hang an, owo won ti han ju. Egberun mejila (#12,000) naira ni eyokan ninu won. Bo tile je pe omo mi ko feran ki n maa toro owo sugbon ko si nnkan ti mo fe e se mo bayii ju ki n soro sita lo, nitori pe mi o le da se. Mo ti loo ba enikan lagbegbe Meiran nipinle Eko, ti eni naa so pe oun yoo gba idaji milionu (#500,000) naira lowo mi. se eyin naa ri ara nnkan ti mo n la koja bayii.

Nipa awon to ti ran mi lowo, Gomina Ibikunle AMosun tipinle Ogun ti se bebe fun mi ri, o ti fun mi lowo nigba kan ri, bee lo tun selerin fun mi pe oun yoo sabewo si mi, to si mu ileri e se. Yato si Amosun, Gomina tele ri nipinle Eko, Babatunde Fashola naa ti se daadaa si mi. Ilu Meka lo wa, to ti gbo iroyin aisan mi, to si ran awon eeyan pe ki won wa a wo mi, awon to ran wa lo mu mi lo si First Cardiology to wa ni Ikoyi, bee lo tun fun mi lowo. Bee ni Gomina ipinle Oyo tele, Oloye Alao Akala leni to koko fun mi lowo. Mo dupe lowo gbogbo won, sibe-sibe, mo si n nilo iranlowo yin.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI