ASIWAJU RERE NI ADEBUTU - WILLIAMS - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 23, 2018

ASIWAJU RERE NI ADEBUTU - WILLIAMS

Aare egbe akekoo ileeko giga ti Olabisi Onabanjo (OOU), Komureedi Adeosun Williams ti sapejuwe Onarebu Ladi Adebutu to n soju ekun Ogun East nile igbimo asofin kekere (House of Representative) niluu Abuja gege bi asaaju rere to se e fokan tan, eni to ye lati di gomina ipinle Ogun lodun 2019.


Ninu leta kan to fi ranse si Onorebu Adebutu tawon eeyan tun mo si LADO, eyi ti eda e te AWIKONKO lowo lo ti gboriyin fun Adebutu awon akitiyan ati ipa to n ko lori awon odo, paapaa awon akekoo jakejado ipinle Ogun ati lorileede Naijiria kaakiri.

Aare egbe akekoo naa tun so pe oun ko le sai fi idunnu oun han si ore awon araalu naa pelu bo se gbaruku ti eto ifigagbaga laarin awon akekoo kan tawon ti gbe kale lati bi ose meloo kan seyin, eyi ti yoo pari ni ola, ojo kerinlelogun osu yi.

Eto ifigagbaga naa ti won pe akori e ni 'Akekoo fun Isejoba to dara', iyen Student for Good Governance la gbo pe won yoo se ninu gbongan ti OOUTH to wa niluu Sagamu.

Siwaju sii la gbo pe Aare naa, Komureedi Adeosun Williams pelu iko to n ba a sise loo ba Onorebu Adebutu lalejo lati so awon ipenija tawon odo n koju ati awon ona ti le gbe e gba lati yanju e.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI