OGOJI ODARAN FOJU HAN LOGBA OLOPAA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 23, 2018

OGOJI ODARAN FOJU HAN LOGBA OLOPAA

Lonii ni ileese olopaa ipinle Ogun labe Komisana, Ahmed Iliyasu foju awon odaran ti ko din ni ogoji han fawon oniroyin, eyi ti AWIKONKO naa je okan lara won.


Opo awon oluworan to wa nibi eto naa lonii ninu ogba olopaa to wa ni Eleweran, Abeokuta ni won lanu sile, ti won ko le pa a de nigba ti won ri bawon odaran naa se n soro, latari awon ona ti won n gba pa awon eeyan lekunjaye.


Lara awon ogbologbo adigunjale ati odaran ti won foju won han ni; Kayode Oreneye, Lateef Folami, Benjamin Oforitse, Yusuf Owoyele, Tunde Owoyele, Itunu Abisoye, Muyiwa Talabi, Tunde Adeyemi, Korede Pariosho, Dayo Johnson, Segun Saka, Niyi Adeshina, Michael Oluwaseun, Afolabi Ismail.


Awon min in ni; Gbenga Ogunsanya, Quam Olubodun, Idowu Olasunkanmi, Gafar Jelili, Olawale Olowu atawon min in.

Nigba to n soro, Ahmed Iliyasu so pe gbogbo igba loun yoo maa tenu mo on pe oun ko setan lati gba iwa odaran laaye nigba toun ba si n je Komisana olopaa, bee lo gbawon osise ileewosan lamoran wi pe ki won rii daju pe won n gba awon ti won ba gbe ogbe ibon wa si osibitu laaye, ki won si maa fi to awon olopaa leti lesekese nitori pe opo awon odaran ni won n gbe ota ibon salo basiri won ba ti tu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI