Be o ba gbagbe, lodun meji seyin ni Mide Abiodun to je omo oloogbe nni, Funmi Martins lo ko o sori ero ayelujara pe oko oun ti pa oun atawon omo yi, o si ti ba obinrin min in lo, ko toju oun atawon omo mo, ko si mo bawon se n gbe igbe aye awon.
Oro naa da awuyewuye ati ariyanjiyan to po sile laarin ololufe won, ti onikaluku si n so nnkan ti oju won ko to, sugbon ni bayii, Afeez funra e ti je ko di mi mo pe awon ore iyawon oun ti won fe da igbeyawo won ru ni won gba a lamonran buruku pe ko soro naa sita, kawon si le pin ya.
Afeez so pe "Ko si idile ti ko nii ni adojuko, sugbon igbese ti toko-tiyawo ba gbe lasiko naa lo maa sapejuwe ibi ti won n lo. Die lo ku kawon ore da igbeyawo wa ru, amonran ti ko dara ni won gba iyawo mi. Bi mo se n baayin soro, oun naa si n kabamo lori awon iwa to hu atawon oro to so nigba naa.
"Toko-tiyawo maa ja, sugbon ko ye kawon ara ile keji gbo sii. A ti se asise ti wa, a si ti kogbon ninu e. A o gbadura fun iru e mo titi aye."
Bee lo so pe, bo tile je pe Musulumi tooto loun, sibe, oun ko nii lokan lati fe ju iyawo kan soso lo, nitori pe oun ko fe wahala fun emi oun.
Ninu oro e, o so pe "Baba mi ko gbiyanju lati fe iyawo meji nitori eeyan jeje n, yi emi naa si n tele ipase e. Bo tile je pe Kuraani wa faaye gba a pe ka feyawo ju eyokan lo, sugbon emi o nife sii nitemi. Opo wahala lo maa mu wa, ti mi o si lemi e."
No comments:
Post a Comment