E JE KI EMI AWON OMO KEKEEKE SE PATAKI SI YIN - ADEBUTU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Sunday, May 27, 2018

E JE KI EMI AWON OMO KEKEEKE SE PATAKI SI YIN - ADEBUTU

Bi a ti n se ayajo ayeye ojo awon omo kekeeke kaakiri agbaye, Onorebu Oladipupo Adebutu to n soju ekun Remo nile igbimo asofin kekere niluu Abuja ti gba ijoba orileede yi labe Aare Muhammadu Buhari lamonran pe ki won wa ona ti won yoo gba lati tubo fi maa daabo bo awon ogo weere, iyen omo kekeeke.



Adebutu lo soro yi laaro oni lakoko to n ki awon omo kekeeke lorileede Naijiria fun ati ayajo ojo ayeye won.

O ni ki ijoba ibile, ipinle ati orileede mura gidigidi lati wo awon ona min in ti yoo tun je anfaani lati daabo bo emi ati dukia awon omo naa nitori pe awon gan an ni ojoola ti a n foju sona fun.

Nigba to n kanminu pupo lori ipo ti eto aabo orileede yi wa lasiko yi, Onorebu Adebutu so pe edun okan lo maa n je foun nigba toun baa n gbo bawon ajinigbe se n fojoojumo ji awon omo kekeeke gbe, ti won si n lo won fun etutu atawon nnkan min in.

Bee lo tun kanminu pe bawon gendekunrin atawon agbalagba alailojuuti tun se n fipa bawon omo kekeeke lasepo, ti won n fipa ja ibale awon tojo ori won ko tii to odun mejidinlogun (18) tun je nnkan ibanuje to n ya oun lenu pupo.

Adebutu so pe eto aabo, paapaa aabo emi awon omode gbodo je nnkan ti yoo je ijoba logun pupo, ti won yoo si wa ona abayo sawon isele to n dojuti ni naa.

Bakan naa lo tun gba awon obi, alagbato atawon oluko lamonran pe ki won tubo maa gbiyanju lati maa ko awon omo naa ni eko to ye looto, eyi ti yoo je ki won ye ni eni amuyangan lawujo orileede yi ati nibikibi ti won ba ti ba ara won kaakiri agbaye, lati le gbe ogo Naijiria ga.

O ni ona ti awon omo naa yoo gba fi wulo fun ogo Naijiria lo ye ki awon obi, alagbato atawon oluko maa wa ni gbogbo igba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI