Ayederu soja meji dero atimole l'Abeokuta - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 8, 2018

Ayederu soja meji dero atimole l'Abeokuta

Yoruba bo, won ni ojo gbogbo ni t'ole, ojo kan soso ni t'olohun, eyi gan an lo lo nibamu pelu basiri awon ayederu soja meta ti won n lu awon araalu ni jibiti se tu, ti won si ti n ka boroboro bi eye awoko ni tesan olopaa bayii.

Abayomi Amos Akanji, Adebayo Rasheed Oladimeji ati Lawal Musa Akinmoye la gbo pe won da awon araalu laamu, ti won si n fipa gbowo lowo won ladugbo Adatan si Bode-Olude niluu Abeokuta, asiko ti won n fipa gbowo lowo okunrin olokada kan lowo te okan lara won.

Kii se pe asiri won dee de tu sawon olopaa lowo, ohun ta a gbo ni awon araalu to fura si won pe ayederu ni won ni won loo ta awon olopaa lolobo, ti oga olopaa Adatan, Ogbeni Joshua Olajide si ran awon omose e lati loo sewadi won.

Nigba tasiri won maa tu, Abayomi lowo koko te lojo Tusde ose to lo lohun, iyen lojo ketadinlogun osu yi, nigba ti won ri ninu aso soja ti ko soruko lara e, lo mu ki won bere sii foro wa a lenu wo, ti ko si le dahun awon ibeere naa.

Bo se fe e salo lawon olopaa naa ba fibon hale mon on pe awon yoo fibon fo lese, ko too duro pe ki won se oun jeje, ati atimu lo sun oun debe nitori pe opolopo ise lojn gbiyanju lati se sigbon ti ko si ona abayo.

O ni je ko di mi mo fawon olopaa pe oun nikan ko loun n sise naa, awon meta ni, ati pe se loun ji aso naa ka lori waya nigba toun loo ki enikan ni baraaki awon sona, oun si ti fi gbowo repete lowo awon eeyan nitori won ko mo pe oun ko kose naa rara.

Leyin ose kan gbako, iyen lojo Tusde to koja yi lowo to o sese te Rasheed ati Lawal lakoko tawon naa n lu jibiti lati gbowo lowo awon eeyan to n koja lo.

AWIKONKO gbo pe se lawon eeyan bere sii fepe rabande-rabande ranse si won nigba towo olopaa te won nitori ta a gbo pe won tun n fipa gbowo lawon ileepo kaakiri, paapaa lasiko owongogo epo pentiroolu ki won to o le je ki moto tabi okada wole ra epo.

Lesekese tiroyin naa ti kan si Ahmed Iliyasu to je Komisana olopaa lo ti pase pe oun fe e foju kan won, nigba to si ri won lo ni o see se ki won tun ti hu awon iwa odaran min in, nitori naa lo fi so pe ki won tare won si eka ileese won to n sewadi odaran, iyen CIID lati tubo foro wa won lenu wo daadaa.

Bee lo so fun won pe iwadii naa ko gbodo pe ki won too lo foju won bale ejo. O wa ro awon araalu pe ki won ma se maa so pe ko si nnkan to kan won nigba ti won ba kofiri awon afurasi odaran, eyi ti ko ni je ki won fi to ileese olopaa leti nitori pe alaafia ilu, aabo emi ati dukia awon araalu lo je won logun pupo, toun ko si ni faaye gba iwa odaran lasiko toun ba si n je oga olopaa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI