Nibi ti olokada ti n le moto lo ti pade iku ojiji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 8, 2018

Nibi ti olokada ti n le moto lo ti pade iku ojiji


Kani okunrin olokada kan ta a ko tii mo oruko e dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan mo pe ise pajawiri ti won pe e si maa pada sakoba fun un lojo naa, boya ko ba ma ti se e, tabi ko ma dahun nigba ti won pe e.

Beeyan ba je ori ahun, to ba de agbegbe iyana Amolaso nitosi Kuto lojo Monde ose to koja lo lohun nibi ti tirela ti te olokada naa, ti ese e si kan lesekese, eni naa yoo ba a kaanu.

Ni nnkan bi aago mewaa aabo aaro la gbo pe olokada ta a ko tii mo oruko e dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan n fi okada sise oojo e gba agbegbe Kuto koja lo, sa dede ni won so pe okunrin kan da a duro nitosi Cultural Centre pe ko gbe oun.

Bo se gbe e ni won so pe okunrin naa so fun olokada yi pe ko ba oun le tirela to ko lu moto oun, to si ti ba a je koja siso, toun naa ko si ro o leemeji, to gba to tirela naa leyin.

A gbo pe bi won se de iyana Amolaso ladojuko ile epo kan ta a foruko bo lasiri ni won so pe olokada naa fe e gba egbe e, ko si le bo siwaju e, sugbon to je pe abe taya e lo ko si.

Bo se ku die ki olokada naa ko sabe taya tirela naa ni won so pe okunrin to wa leyin e ti fo danu, to si f'apa bo, ti olokada ni tie ko save tirela, tiyen si te ese e kan sile.

Lesekese la gbo pe ati okunrin to ran olokada nise de torutoru, ati okunrin to wa tirela naa ti na papa bora, ti ko seni to mo bi won se rin in lakoko tisele maa sele.

Nibe lawon toro naa soju won ti ranse sawon olopaa atawon TRACE lati wa a gbe olokada naa, sugbon nnkan to je iyalenu ni pe fun bi wakati kan aabo la gbo pe awon olopaa atawon TRACE naa ko ri nnkan se sii, ko too di pe awon tisele naa soju won fi agidi da moto taisi kan duro lati bawon gbe e lo si jenera osibitu Ijaye fun itoju.

Awon kan to n fehonu won han lori iwa ti eni to wa tirela naa hu fe e dana sun tirela yi, sugbon awon olopaa atawon TRACE ni won ko gba fun won, ti won ni awon yoo sewadi.

AWIKONKO pada gbo pe awon osise osibitu jenera so pe awon ko le gba a, eyi lo muu ki won gbe e lo si FMC to.wa ni Idi-Aba, nibe lo dake ki won to o gbe wonu woodu.

Ojo keji la gbo pe won sin in nilana musulumi ladugbo Amolaso. A tun gno pe iyawo meji pelu omo meji lo ni, yi okan ninu awon iyawo naa n gbe ladugbo Ake, sugbon ta a ko tii mo oruko e dasiko ta a sakojopo iroyin yi tan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI