Baba agbaaya to fipa bomodun metala sun dero atimole - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 8, 2018

Baba agbaaya to fipa bomodun metala sun dero atimole


Epe rabande-rabande lawon to gbo nipa baba agbalagba eni aadorin odun (70) to fipa ba omoomo inu e sun si n fi ranse si baba naa ti won pe oruko e ni Adefuye Emmanuel Teslim.

Ojo kejilelogun osu ta a wa yi la gbo pe Teslim to n gbe ladugbo Parapete niluu Ago-Iwoye ranse pe omo naa ta a foruko bo lasiri pelu etan wi pe oun fe e ran an nise, tomo naa si sare lo ba a lai mo pe se ni baba agbaaya naa fe e fipa ba ojoola oun je.

Won ni bimo naa se de odo Teslim lo tan an wole pe ko wa a lo gba owo ninu yara, tiyen naa si tele wole, bomo naa se wole ni Teslim sare tilekun leyin, to si fipa bo pata omo yi, to si bere sii ko ibasun fun karakara.

Awon to gbe iroyin naa s'AWIKONKO leti je ko ye wa pe se ni Teslim tun hale mo omo naa pe ko gbodo so fawon obi e, ati pe se loun yoo gbemi e to ba fi le so fenikeni.

Isesi omo yi lo mu ifura dani fun iya e, Mariam Kareem to sinbere sii foro wa a lenu wo, ko to o di pe o pada jewo fun un, lesekese tomo naa ti jewo la gbo pe Matiam ti pariwo sita fawon araadugbo, ti won si loo fa a le awon olopaa Ago-Iwoye lowo.

Lati fidi e mule lo mu kawon olopaa loo sayewo fomo naa ni osibitu kan ta a foruko bo lasiri, ti esi ayewo ti won se jeri sii pe se ni won fipa ja ibale omo naa.

Bo tile je pe baba agbaaya naa koko n so pe iro ni won pa mo oun, to si pada jewo pe looto, ki won se oun jeje nitori pe ise esu. O loun ko le so pato emi to gbe oun wo lojo naa, ati pe leyin toun se kinni naa tan loju oun to o pada la pe oun ti daran.

Abimbola Oyeyemi to je agbenuso fawon olopaa fidi isele naa mule, to si so pe Komisana awon ti tare baba naa sodo eka olopaa to n ri si lilo omo nilokulo ati fi’fomo se oowo eru lati tesiwaju ninu iwadii, bee lo seleri pe lai pe ni baba naa yoo foju bale ejo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI