E je ka maa wa idagbasoke ati isokan egbe – Komureedi Azeez - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 12, 2018

E je ka maa wa idagbasoke ati isokan egbe – Komureedi Azeez

Komureedi Adeyemi Azeez to je okan pataki lara awon omo egbe to n soowo igi nipinle Ogun, iyen Irewolede Plank Sellers And Wood Workers Association to wa ni Lafenwa niluu Abeokuta ti gbawon eeyan lamoran, paapaa awon ti won jo n sise kan naa pe ki won je ki alaafia ati idagbasoke egbe je won logun, di po ki won maa gbe aheso kaakiri.


Adeyemi Azeez to je alaga eto ayeye idanilekoo olojo kan soso ti won se fawon omo egbe onigi nipinle Ogun lo soro yi nibi idanilekoo naa to waye ninu gbongan awon oniroyin to wa ni Iwe-Irohin, Oke-Ilewo lojo Tosde to koja yi.

O so pe egbe awon ko pin si meji, eyokan soso ni, ati pe awon to n gbe aheso kaakiri ni won n da awuyewuye sile laarin awon araalu.

Ninu oro e, o ni “Se e ri awuyewuye ati aheso oro lo n ti enu awon to je pe won ko fe ilosiwaju, bo tile je pe onikaluku won lo mo idi ti won fi n se be. Mo fi n da yin loju pe egbe Plank Sellers Association, eyokan soso ni wa. Sugbon eyi ti a n se yi, iyen Irewole Planks Sellers And Wood Workers Association, orisirisi awon eeyan lo wa ninu wa, bi awon to n ta igi, awon to n fi ero la igi, awon to n ta ohun elo ile, iyen Building materials ati bee bee lo.

“To ba je pe se la ko ara wa jo bii egbe kiloobu, awon min in le ro pe a fe maa lo lati fi lo si pati ni, iyen la se je ki won mo pe kii se fun pati, bi ko se ilosiwaju awaarawa. Egbe wa ko pin rara, sugbon a ni egbe nla kan to je pe abe e ni gbogbo wa wa.”

Nigba to n soro nipa eto idanilekoo ti won se naa, Komureedi Azeez je ko di mi mo pe akoko iru e ni eto naa, to si je pe odoodun lawon yoo maa gbe kale fawon omo egbe, lati le maa tan imole sawon ohun to ba sokunkun si won. O ni kii se pe ki won maa ni erongba wi pe ode ariya ni won da egbe naa sile fun.

Bee lo tun so pea won tun gbe eto kan kale legbe kan ninu eto idanilekoo yi lati maa fi se iranlowo fawon alaini nipa irolagbara bii owo atawon nnkan ti won le maa lo lati maa fi sise ki won le maa ri owo fi jeun atawon nnkan ti won ba tun fe e se nigbesi aye won.”

Lojo naa ni won fawon marun un kan ti won nilo iranlowo ni owo to joju, bee ni won tun fawon min in to ti ko ipa to joju lawujo ni ami eye, iyen awoodu lati mo riri ise takuntakun ti won n se.

Oludanilekoo ojo naa, Otunba Abayomi Odunowo nigba to n soro lori koko pataki ojo naa, iyen “Human Being And The Challenges of Life”, o tan imole sawon ipenija to n dojuko awon eeyan, paapaa awon onise owo, bee lo si so orisirisi ona abayo.

Awon to gba ami eye lojo naa ni: Otunba Abayomi Odunowo (Yomi Cash); Onorebu Taiwo Oludotun; Onarebu Lanre Jaji; Onarebu Bolanle Jelilat Ajayi; Alaaji Akesire Eji; Alaaja Silifat Adeshina Opara; Alaaji Fatai Adebowale ati Ogbeni Hezekiah Adekunle.

Eto idanilekoo naa ni won pe akori e ni “Effective Management and Understanding Life Challenges.”

Lara awon to tun wa nibi eto idanilekoo naa ni: Komureedi Wole Soku. Awon igbimo to sagbateru eto naa ni Akinyemi Sulaimon; Mosunmola Ogunpola; Esther Olayemi; Olukunle Mariam; Ibraheem Nojeem Asore; Femi Adenekan; Basirat Orisasanmi ati Gafar Lawal.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI