Tobiloba Ipense ti foju bale ejo o - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 11, 2018

Tobiloba Ipense ti foju bale ejo o

Lojo Tosde to koja yi ni Ogbeni Tobiloba Ipense to ni soosi Kerubu ati Serafu ti Holy Garden to wa ni Papa/Ewekoro la gbo pe o foju bale ejo, pelu okan lara awon alabasisepo e Oluwakemi Ishola.
Be o ba gbagbe, Tobiloba Ipense ni pasito ti won so pe o seku pa Iyaale ile kan, Raliat Sanni to ti bimo marun un, to si loo ri mole sinu soosi e lati fi se oogun aworo ni nnkan bi osu meji seyin.
Gege ba a se gbo, esun meta otooto ni won fi kan Tobiloba, lara awon esun naa ni pe esun apaaya, ati gbigbe oku eeyan pamo ti won loo lodi si ofin orileede yi.
Bo tile je pe adajo naa, Ogbeni S. M Banwo so pe ko si aaye lati gba beeli Tobiloba, sibe o gba pe ki won gba beeli Oluwakemi ni milionu meji ataabo (2.5) naira pelu oniduro meji.
Bee lo sun igbejo si ojo ketadinlogbon osu keje odun yii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI