Eleso fibinu soro sawon to n ba ise tiata je - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, May 10, 2018

Eleso fibinu soro sawon to n ba ise tiata je


Eni to ba wa nibi ti Gbajumo osere tiata apanilerin nni, Ogbeni Adeoye Adewale tawon eeyan mo si Eleso ti n soro lale ojo Fraide ose to koja niluu Abeokuta yoo mo pe inu e ko dun sawon osere tiata to so ise naa di idakuda mo awon agbaagba nidi ise naa lowo, eyi to mu ki won sa seyin.

Eleso tawon eeyan tun mo si Enu N Ja Waya lakoko to n B'AWIKONKO soro fibinu so pe ibanuje lo maa n je foun lakoko toun ba n wo awon sinima to n jade lasiko yi, to je pe se ni won a maa ba ara won sun nibe, won tun maa gbe omu won sita faraye, ti ko si ye ko ri bee.

Ilumookan aderinposonu naa ni bo tile je pe opolopo igba lawon agbaagba kan ti pe won sakiyesi, ti won tun gbe idanilekoo kale fun won lawon asiko kan, sibe se lo tun n buru si nitori pe won fe e maa sebi awon oyinbo, ti won si n gbagbe awon asa ile Yoruba.

O ni bi won baa n ju abebe soke nigba igba, ibi pelebe ti yoo maa mu pada sile naa ni pe won ko le yi iwa buruku owo won pada nitori pe onisekuse lo po ju ninu won, ti ko seni to le ba won soro.

Bee lo so gbe ile ti won ti n jade sidi ise tiata laye won ti baje ti won si wa n fi koba awon ti won ba nidi ise naa nitori pe awon ko le gbagbe ipile rere tawon baba bii Oloogbe Ogunde, Kola Ogunmole, Oyin Adejobi, Duro Ladipo atawon min in bee fi sile lo.

Eleso ni kii se tenu pe se ni baba Adebayo Faleti ronu ku nigba to ri ibi ti won n gbe ise tiata gba laye ta a wa yi, nitori pe ko fe e maa ri irikuri mo lo se tete pada sorun to ti wa, ati pe lopo igba ti Faleylti wa laye, ti won ba beere lowo e pe nibo ni won ba ise naa de, pelu ibanuje lo ma fi n dahun.

O nidi niyii tawon fi niloo awon oju tuntun, iyen awon ti won mo nnkan ti won n se, ti won ko nii je ki asa ati ise Yoruba parun, to mu koun gbe ajo kan dide lati wa awon oju tuntun sinu ise naa.

Bakan naa lo so pe ko seni to le gba won lamoran nipa nnkan ti won maa se fun won nitori pe owo ti won n wa nibe ati ise asewo ti won fe e se lo je won logun ju oju buruku tawon araalu yo fi maa wo won lo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI