Ile ejo tu igbeyawo odun mejidinlogun laarin pasito atiyawo e ka - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 8, 2018

Ile ejo tu igbeyawo odun mejidinlogun laarin pasito atiyawo e ka


Lojo Tusde ose to koja yi ni ile ejo koko-koko to fikale si adugbo Ake niluu Abeokuta tu igbeyawo odun mejidinlogun (18) to wa laarin iranse Olorun kan, Ogbeni Moses Oseyemi atiyawo e Arabinrin Temitopo Oseyemi ka, ti won si tun pase pe ki okunrin naa ko awon omo e mefeefa sodo lati maa toju won.

Kii se pe ile ejo naa deede wo sunsun lati tu igbeyawo naa ka, sugbon aiyoju iyaale ile naa leemeeta otooto ti won fiwe pe e wa si kootu lo mu kawon adajo naa, Oloye Akande O. O ati Onarebu Arabinrin Majekodunmi H. I fagile igbeyawo na pe ki onikaluku won maa lo lai si wahala.

Nigba to n bura niwaju ile ejo pelu bibeli, Moses so pe “Adugbo Sabo niluu Abeokuta ni mo n gbe pelu awon omo mefa, ise Pasito ni mo n se, mo si tun n sise owo pelu e. Mo fe ki ile ejo tu wa ka, ki won si ko awon omo mi fun mi lati maa toju won, bo tile je pe akata mi ni won wa. Orisirisi iwa adojutini niyawo mi n hu, to si maa n ba mi fa wahala to po. Lojo to maa ko eru e jade lodun 2016, se lo loo gbe omo wa abigbeyin toun ti pe odun meji aabo bayii sile fun araadugbo pe oun n bo, latigba naa ni ko ti yoju, to je pe okan lara awon omo ijo mi lo n ba mi toju omo naa.”

O ni ko to o di pe oun wa si kootu loun ti loo fejo e sun awon ebi, nitori pe awon loun maa n pe nigba tawon ba ti ni ija, sugbon nitori ko si ayipada lo mu koun pinu lati ko o sile labe ofin. Bee lo so pe o see se ko ti fe okunrin min in nitori pe latigba to ti ko omo sile foun ni ko ti yoju lati wo alaafia awon omo e.

Nigba to n gbe idajo kale, Oloye Akande O. O ati igbakeji e, Onarebu Majekodunmi H. I. je ko di mi mo pe bawon ko ba ti ri eni ti won fesun kan leemeeta otooto tawon ba ti fiwe pe, a je pe eni naa ti gba kamu pe kile ejo se nnkan to ba ye.

Oloye Akande so pe ojo kejilelogun osu keta ati ojo kokandinlogun osu kerin lawon fiwe pe e, tawon si tun reti e lati wa a so tenu e lojo Tusde naa, sugbon ti ko yoju, o ni ko si nnkan tawon yoo se ju kawon tu won ka gege bi oko se n fe lo.

O wa pase pe yato si pe oun tu won ka labe ofin, igbakigba ti Temitope ba fe e ri awon omo e lo letoo lati ri won, ti ko si gbodo si wahala laarin won, ati pe ojokijo ti Temitope ba ti wa a fa wahala, ki won fi to awon olopaa leti lati tii mole.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI