Onarebu Adebutu to n soju ekun Remo nile igbimo asoju-sofin niluu Abuja lo soro yi lakoko bawon araalu soro lati fi saami ayeye eto isejoba awaarawa olodoodun.
Adebutu so pe kawon omo orileede Naijiria ma se so ireti nu pe won ko le je ajegbadun eso ijoba awaarawa lorileede yi paapaa nipinle Ogun mo, nitori pe asiko naa ti fe e de ti won yoo maa je mudunmudun eto isejoba awaarawa.
O ni o seni laanu pe asiko to ye kawon araalu maa se ajoyo iru ojo bayii lo je pe inu ironu ebi to n pa won lojoojumo ni won wa, nitori pe ayipada tawon adari orileede yi seleri fun won ko ni won ri.
Adebutu so pe ojoojumo ni airise se awon odo n peleke sii, ti ise ati osi n bawon araalu mule, ti ipaniyan olojoojumo ko dawo duro, ti emi ati dukia awon araalu si tun n fojoojumo sofo danu.
Bee lo so pe ojoojumo nijoba orileede yi n fi eto awon araalu dun won, ti ko si ye ko ri bee, nitori pe aabo emi ati dukia awon eeyan gbodo je ijoba logun pupo.
Nigba to n gbawon araalu lamonran fun idibo odun 2019 to n bo lona, Onarebu naa so pe onikaluku lo ni ojuse lati se lati rii pe ijoba to n se ti awon araalu bo sipo ijoba lodun 2019, iyen nipa gbigba kaadi idibo alalope (PVC) won ki asiko to o lo.
No comments:
Post a Comment