OSELU BERE: WON LAWON OMO EYIN YAYI TI SALO SODO ADEBUTU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, May 30, 2018

OSELU BERE: WON LAWON OMO EYIN YAYI TI SALO SODO ADEBUTU

Bi iroyin to te AWIKONKO lowo lai pe yi ba fi le je otito, a je pe afaimo ki Seneto Solomon Olamilekan Adeola tawon eeyan mo si Yayi, eni to n soju ekun Lagos West nile igbimo asofin agba niluu Abuja ma padanu ibo e sowo omo Baba Ijebu, iyen Onarebu Oladipupo Adebutu, topo eeyan mo si LADO lodun 2019.


Ohun ta a gbo ni pe lojo Tusde to koja yi ni LADO to n wa gbogbo ona lati di gomina loo si ijoba ibile Abeokuta North lati loo bawon omoleyin e soro fun imurasile ibo gomina ipinle Ogun lodun 2019.

Nibe la ti gbo pe awon omoleyin Seneto Yayi toun naa n gbero lati jade dupo gomina ipinle Ogun lodun 2019 to wa ni agbegbe yen ti sare lo lati loo pade LADO lati loo kii.


Nigba ti won ni won rii bi ipade naa se n lo si, ni won ti bere sii pe awon omo egbe won toku pe ki won tete maa bo, omo baba Ijebu ti wa layika, kawon tete wa a so ipinu won lati tele fun idibo odun 2019 to n bo lona.

AWIKONKO gbo pe awon ti ko din ni ogorun meta (300) lawon omo leyin Yayi ti won je omo egbe oselu APC ni won so pe awon ko se egbe naa mo, ati pe awon ko tele Yayi tawon n tele tele mo, ti won ni LADO leni tawon nife sii lati gbaruku ti.

Okan lara awon ti ipade ita gbangba ti won se ladugbo Elega niluu Abeokuta soju e, eni to ni ka fi oruko boun lasiri je ko ye wa pe awon adari egbe omoleyin Yayi bii Onarebu Gani Adebisi, Alaaji Farsi Ajigbare, Arabinrin Fatima Akindele, Alaaji Abati Suraju (Surry), Alaaji Fatai Adegbola atawon min in ni la gbo pe won lewaju awon eeyan naa, ti won si n korin pe awon ko ba olote se mo.


Won ni pataki nnkan tawon eeyan naa n so ni pe awon ko le tele eni ti ko tii mo inu egbe oselu to fe e gba jade dupo gomina mo, nitori pe ko si aaye fun ninu egbe oselu APC nitori wahala to wa laarin oun Gomina Amosun.

A tun gbo pe awon esun ti won lawon eeyan naa fi kan Yayi ni pe se lo dabii pe o n tan awon je ni, nitori pe awon ko tii mo boya o si maa pada siluu Eko, nitori naa kawon tete gbaruku ti eni ti aye n fe ti e, iyen Onarebu Adebutu.

Gbogbo akitiyan lati gboro lenu Ogbeni Kayode Odunaro to je agbenuso fun Seneto Yayi, paapaa lori oro iroyin lo ja si pabo, nigba ti a pe e, ko gbe foonu, bee ni ko si pe wa pada.

AWIKONKO tun fi atejise ranse sii, sibe ko tii da esi atejise wa pada titi ta a fi sakojopo iroyin yi tan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI