LAGBO AMULUDUN: ADEBUTU S'ATILEYIN FAWON ODO NAIJIRIA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, May 24, 2018

LAGBO AMULUDUN: ADEBUTU S'ATILEYIN FAWON ODO NAIJIRIA

Asoju ekun Remo nile igbimo asofin tiluu Abuja, Onorebu Ladi Adebutu ti so pe oun setan lati satileyin alailegbe fawon odo orileede Naijiria, paapaa leka eto amuludun, iyen Entertainment Industry.


Adebutu to tun je adije sipo gomina ipinle Ogun lodun 2019 lo soro yi lojo Wesde to koja yi lakoko ti okan lara awon gbajumo olorin takasufe lorileede yii, Raoul John Njeng-Njeng topo eeyan mo si Skales loo sabewo sii niluu Abeokuta.

Ogbontarigi oloselu naa je ko di mi mo pe lati le je ki awon odo Naijiria je mudunmudun eto isejoba awaarawa, oun ti setan lati gbaruku ti won, nitori pe ipa ti won n ko nigbesi aye opo awon araalu ko kere rara, amuludun ti ko se e gboju fo da ni won je.

Siwaju si ni Adebutu to je okan lara awon omo gbajugbaja onisowo nni, Adebutu Keshington tawon eeyan mo si Baba Ijebu tun je ko di mi mo pe bo tile je pe oun ko fe e soro naa sita gbangba, sugbon toun ko le ma soro lori e nigba ti ibeere ti jade nipa e.


O so pe oun gboriyin fun ise takuntakun ti Skales n se nipa ona to n gba sagbekale awon orin e, toun si fe kawon jo fowosowopo lori ona ti abala eto ariya yoo fi gbe awon ohun amusoro ipinle Ogun soke, ti yoo si tun mu idagbasoke ba eto oro aje ipinle naa.

Ninu oro e, LADO so pe "O wun mi ka se ipade yi ni bonkele lai je kawon eeyan to wa nita mo sii, lati le je ki ipinu ti mo ni le tete wa si imuse. Mo mo riri ipa awon odo lawujo, paapaa bi idagbasoke se n de ba agbo amuludun, iyen ariya lorileede Naijiria.

"Nnkan ti mo fe e se ni pe, mo fe e da sii lati le loo fun idagbasoke ati ilosiwaju ipinle mi (Ogun), pelu ajosepo Skales, eni ti mo gba pe o kun oju osuwon, o si lebun repete funra e."

Nigba to n soro, Skales funra e so pe bo tile je pe oun ko tii foju kan gbajumo Onarebu naa ri, sugbon toun n gbo awon akitiyan pelu atileyin alailegbe to n se fawon omo ipinle Ogun, sugbon ti inunoun dun lati joo jokoo soro.

O ni bo se n sagbateru awon odo ipinle naa nipa owo atawon nnkan min in, paapaa eka eto eko nipa fi fun awon akekoo jade ni eto eko ofe (Scholarship) lasiko to fi wa nijoba ko le je ki oruko e pare.

Bee lo so pe idunnu nla lo je foun lati je okan lara awon ti yoo ba Adebutu sise ninu eto idibo to n bo lona.


Saaju akoko yi ni LADO ti menuba a laato ano lori redio Sweet to wa niluu Abeokuta lakoko to n dahun ibeere olokan-o-jokan lati enu Samuel Olojede pe asiko re e tawon odo orileede gbodo kopa ninu oselu, tawon naa si gbodo gbe apoti lati dupo.

O ni nnkan ti yoo dun mo oun ninu ni koun ri awon odo ti ojo ori won bere lati ogun odun, ogbon odun ati ju bee lo pe kawon naa di ipo mu leka eto oselu bii Komisana, agbenuso, amugbalegbe ati bee bee lo.

Bee lo ro awon odo pe ki won tete loo gba kaadi idibo alalope, iyen PVC won ko too digba ti idibo yoo bere ni pereu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI