Nitori owo LAPO ati agbere, Labake fe e ko oko e sile - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 8, 2018

Nitori owo LAPO ati agbere, Labake fe e ko oko e sile


Bo tile je pe kii se oro owo ni iyaale ile kan, Arabinrin Asimiu Labake gbe lo sile ejo koko-koko to wa ni Ake wi pe ki won tu igbeyawo to wa laarin oun ati oko oun, sugbon nigba to n ro ejo e ni asiri oro naa je jade sita, to si se awon ero iworan ni kayeefi.

Ojo Tusde ose ta a lo tan yi ni Labake soro niwaju awon adajo kootu pe odun 2014 loun ti ko eru jade kuro nile oko oun, nitori pe se lo fe e pa oun patapata, ko si maa baa won obinrin min in jaye kaakiri, eyi to mu ko maa ba oun fa wahala lojoojumo.

Labake so pe oun ko tete mo pe oko oun ba omo baba onile awon sun, to tun n ko ibasun fun okan lara awon omo Imaamu Asalatu won karakara, sugbon nigba ti wahala nla kan sele laarin won lasiri oro naa tu jade sita, tawon araadugbo si wa a jeri tako oko oun pe agbere e ti po ju ladugbo, ti ko si seni ti ko le denu ife ko.

O ni nigba tawon pari ija naa loun pe oko oun, Tajudeen Sanusi pe ko je kawon loo gba ile sadugbo min in, tawon si jo panupo gba owo LAPO ti won n ya awon eeyan ladugbo. O ku ola ki won gba owo naa lo so pe egbon oko oun tomo e fe e seyawo pe oun pe oun gbo pea won fe e ya owo, nitori naa tawon ba ti gba owo naa, koun ya won lati lo fi mu aso pati, leyin pati loun yoo si da owo naa pada.

Labake so pe lojo toun gba owo naa, se lawon adigunjale gba owo naa lowo oun, ti oko oun ko si da oro owo naa so, titi toun fi san owo naa ku egberun mewaa naira, ati pe nitori koun ba a le ri owo san loun se kuro nile lati loo wa ise min in se.

O nigba toun maa pada de loun rii pe oko oun ti ta soobu oun, iyen kontena toun n lo, ti ko si ko owo naa kale, sugbon to loo san egberun mewa naira gbese to ku, ti ko si ko owo naa foun, o nironu owo naa lo moun daku tawon araadugbo sis are gbe oun lo si osibitu, sibe oko oun ko yoju lati wa a wo oun. O ni ojo keta toun pada dele loun ko eru kuro nile, toun si wo o pe bi awon ko ba yanju oro naa laarin odun merin, oun yoo jawe fun un.

Baale ile naa, Sanusi so pe oro asodun niyawo oun so nitori pe lojo to maa ko eru e jade kuro nile, alejo kan loun sin jade lo, nigba toun maa pada dele, loun rii pe ile ti mo, awon araale lo so pe iyawo oun ti keru jade. O ni lojo yen, aburo iyawo oun lo wa ki awon nile, asiko naa kisiini loun wa toun n dana lowo.

Awon ta a jo n gbe so pe ki lo de toun ko le beere nnkan ti aburo iyawo oun maa je, toun si dawon loun pe ki lo de ti aburo naa ko le wa a ba oun nibi toun ti n dana, aburo naa lo so pe o bere sii pa asamo moun, to si fibinu soro sii, leyin naa lo so pe oun jade, nigba toun si maa pada dele loun ko baa won mejeeji.

Oloye Akande O. O. nigba ti won soro so pe bo tile je pea won ko le da ejo lojo kan soso, sibe kawon mejeeji loo tun ero won pa daadaa boy a atunse si le wa ko to o di ojo kejidinlogun osu karun un (May 18) ti igbejo min in yoo fi waye.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI