OSOBA, YAYI FI IDIBO EGBE OSELU APC IPINLE OGUN SILE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 19, 2018

OSOBA, YAYI FI IDIBO EGBE OSELU APC IPINLE OGUN SILE

...Bee ni Oloye Adebiyi di alaga egbe APC l'Ogun

Ko si nnkan meji to n je kayeefi fawon omo bibi ipinle Ogun, paapaa awon omo egbe oselu APC lonii ti won se ipade gbogboogbo egbe won, nibi ti won ti dibo yan awon oloye tuntun ti yoo dari egbe naa fun odun merin gbako lori bi Gomina ipinle naa tele, Oloye Olusegun Osoba; Seneto Solomon Adeola, Seneto Gbenga Obadara, Onarebu Adeyemi Adekunle atawon min in to je ti Oloye Osoba ko se yoju sibi eto idibo naa ti won se ni gbagede ayeye June 12 to wa ni Kuto, Abeokuta.

Bo tile je pe Oloye Samuel Aderinsola Adebiyi lo jawe olubori nibi eto idibo naa gege bi alaga egbe oselu APC nipinle Ogun, sibe ohun tawon kan n so ni pe o see se ki Oloye Olusegun Osoba ti fi egbe APC sile lo sinu egbe min in latari bi iduna-dura to se pelu Gomina Ibikunle Amosun ko se wo.

Be o ba gbagbe, lai pe yi ni Oloye Olusegun Osoba atawon omoleyin e bii Seneto Gbenga Kaka loo sepade pelu Gomina Amosun pe kawon pada di eyokan soso, lati le gba alaafia laaye ninu egbe APC.

A gbo pe ko si nnkan meji ti Oloye Olusegun Osoba ba lo sodo Gomina Amosun bi ko se ti erongba e lati fa alaga egbe naa kale, ki won si panupo fa gomina kale, sugbon ti won ni Gomina Amosun ko gba fun un, eyi gan an ni won loo fa ti ko fi yoju sibi eto idibo naa, tawon omoleyin e naa ko si yoju yato si Seneto Gbenga Kaka to wa lati ijebu-Igbo.

Eyi to tun ya awon eeyan lenu ni ti Seneto Olamilekan Adeola tawon eeyan tun un pe ni Yayi, eni to n soju ekun Lagos West nile igbimo asofin agba niluu Abuja toun naa n gbero lati jade dupo gomina ipinle Ogun labe egbe oselu APC lodun 2019, toun naa ko yoju lati wa a farahan gege bi omo egbe, to si je pe ilu Eko ni won ti ri.

Opo awon omo egbe naa la gbo pe won ko yoju sibi eto idibo naa.

Ohun tawon eeyan n so ni pe bi Seneto Solomon Adeola ba a mo pe oun fe e jade dupo lodun 2019 ti ko si nii padanu, ayafi to ba le pada siluu Eko to ti n bo, nitori pe ko si aaye fun ninu egbe APC ipinle Ogun, tabi ko loo darapo mo egbe oselu min in ko to o pe ju, to ba mo pe looto nipo gomina wun oun.

Bi Oloye Osoba ati Seneto Yayi ko se yoju nipinle Ogun lo mu kawon kan maa so pe o see se ki won ti fegbe naa sile, ki won ma si tii fe kede sita pe awon ko segbe mo, sugbon ta a ko tii le fidi e mule.

Kaakiri ijoba ibile Ogun ati ijoba ibile idagbasoke mokanlelogun to wa nipinle lawon omo egbe oselu APC ti yan awon asoju won ti won yoo wa dibo lati yan alaga tuntun fegbe won, ko da a, to fi mo Minisita foro eto oro aje orileede yi, Arabinrin Kemi Adeosun lo wa nibi eto idibo naa ti Ogbeni Peter Obadan ti won fi se alaga eleto idibo.

Saaju ninu oro e, Peter Obadan nigba to n soro gboriyin fun egbe oselu APC ipinle Ogun, paapaa Gomina Amosun fun ise takuntakun ti won n se lati je ki alaafia ati isokan joba ninu egbe naa.

O ni inu oun dun fun ipo toun ba egbe APC ipinle naa nitori pe ko ri be e lawon ipinle min in kaakiri orileede yi. Bee lo so pe ko si iye meji pe egbe APC nikan legbe to wa nipinle naa.

Nigba to n dupe lowo awon omo egbe naa, Oloye Samuel Aderinsola Adebiyi to je alaga tuntun naa so pe inu oun dun lori ona ti won fi gbe eto naa kale, ti ko ni awuyewuye ninu, tawon eeyan si le jeri sii pe oun loun wole.

O loun setan lati mu idagbasoke, ilosiwaju, isokan, ife ati alaafia ba egbe naa, toun yoo si tun tesiwaju nibi ti alaga ana ba a de. Bee lo fokan awon omo egbe bale pe egbe naa ni yoo jawe olubori lodun 2019.

Gomina ipinle Ogun, Ibikunle Amosun naa gboriyin fawon omo egbe, paapaa awon eleto idibo naa fun ise takuntakun ti won se lati rii pe eto idibo naa lo ni irowo-irose.

O gbawon omo egbe lamoran pe ki won rii daju pe won loo gba kaadi idibo alalope (PVC) won, ki won ba a le kopa nibi eto idibo odun 2019.

Lara awon to tun wa nibi eto naa ni Mustapha Gaidam (akowe); Ogbeni Ezekiel lati Taraba; Onorebu Dairo lati Kano; Umar Yahaya lati Kaduna; Dokita Keadese Adeola to se alaga eto idibo odun 2018; Alaaji T.T Ahmed to lewaju awon ajo INEC lati wo bi nnkan se n lo si.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI