SHEIK MUHYIDEEN BELLO S'OKO ORO SAWON ARAALU ORINMERUNMU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, May 19, 2018

SHEIK MUHYIDEEN BELLO S'OKO ORO SAWON ARAALU ORINMERUNMU

Ko seni to de ilu Orinmerunmu lojo Fraide ana, nibi ti okan lara awon agba oniwaasi Musulumi lorileede Naijiria, Fadilat Sheiki Muhyideen Ajani Bello (Allahu Muhyi) ti se idanilekoo Waasi aawe Ramadaani akoko fawon Musulumi ti ko nii mo pe ojise Olohun tooto ni baba naa pelu bo se so awon asiri to n mu ifaseyin ba ilu Orinmerunmu, paapaa esin Islam nibe, ati bi won ko tii se ronu lati pari Mosalasi won ti won ti bere lati nnkan bi aadoje (129) odun seyin.

Sheiki Muhyideen Bello
Sheiki Ajani Bello to so pe bo tile je pe oro wa, sugbon ti ko si aaye lati so o latari awon ibi meji ti won tun ti pe oun si lati wa a gbawon nimoran, iyen ilu Eko ati ilu Abuja to je olu- ilu Naijiria.

Gege b'AWIKONKO se gbo, Alaaji Kazeem Ayinla to je alase ati oludasile ileese Seakam Global Resources Limited to n se oti egboogi Bajinotu (Poka) jade lo sagbateru idanilekoo aawe Ramadaani naa, akoko iru e niluu Orinmerunmu si nii.

Nigba to n soro, Sheiki Ajani Bello so pe ko si nnkan meji to n mu ifaseyin ba ilu naa bi ko se bi won se ko lati gba alaafia, isokan ati laaye laarin ara won, paapaa awon Musulumi.

O ni kaka ki won gbajumo oro esin ti yoo gbe won wo ijoba orun, oro ile (land) ti ko kan won, ile to je pe Olohun lo da a ni won n ja si, ti won pa ara won le lori, to si je pe bi won ko ba jawo, inu ina ni won n lo.

Bakan naa ni agba oniwaasi naa kanminu pupo lori Mosalasi akoko to wa niluu Orinmerunmu, eyi ti won lodun 1889 ni won ti bere e, ti won ko si tii pari e latigba naa titi dasiko yi.

Ninu oro Sheiki Bello, o ni "Eyin ara ilu Orinmerunmu, e beru Olohun, nnkan ti ko da le fi n sere yi. Olohun ni mo pe eyin ti e gba mi gbo pelu igbagbo ododo pe ki e dide. E ko ni itiju nitori pe e ko da Olohun mo. Ko si nnkan meji to gbe mi wa sibi, bi ko se ti Mosalasi ti e so pe e ni nibi yi lo. Wahalahi, nnkan to gbe mi debi niyen.

"Ti e ko ba ri mi ri, sebi e n gbo kaseeti mi, e si n gbo waasi awon agba Musulumi min in? Awon Aafa yin ti e so pe e ni ni won ko so ododo oro fun un yin. Won n ba a yin se ikomojade, won n ba a yin so yigi, gbogbo owo ti won n gba nibe ni won n te mole, ko si eyi ti e fi sile fun Mosalasi.

"Ka ti e wa so pe mo pinu lati ba a yin kirun Jimo, se ibi ti e maa mu mi lo niyen, alainitiju ni yin. Eyin Musulumi Orinmerunmu, e beru Olohun, oju ko ti yin nibi ti e ti n kirun Jimo nibi ti ojo ti maa pa yin. Ko seni to mo ile ti yoo mo oun lojo keji.

"Ile ti e n gbe inu e to je pe yoo pada dahoro to ba ya le n gbajumo, nitori pe awon omo yin ko nii gbe inu e nigba tawon naa ba ko ti won, ti e ko gbajumo ile ti ko nii dahoro nitori pe iran kan n lo, iran kan n bo ni ile Olohun je, eyi to si ye ki e gbajumo daadaa niyen, kawon iran to n bo si le maa sadura fun un yin.

"O ye ki oju ti yin pelu ibi ti e ti n josin fun Eleda yin, e loo wo awon elesin keji bi won se n ko ile ijosin nla kaakiri. E ko ye leni ti a le pe ni Musulumi rara, ati pe Musulumi olodun (seasonal) lo po ninu yin ju awon to n kirun lojoojumo lo. E beru Olohun to le so ile ti e ko dahoro.

"Nkan akoko ti mo ri ni pe eyin araalu Orinmerunmu ko feran ara won, aile-feran ara yin ko nii je ki e ri Anobi to ba di ojo igbedide alikiyamo, eni ti ko si ri Anobi ko le ri Olohun, eni ti ko ri Olohun ko le wo alujono. Be o ba feran ara yin, Olohun ko nii feran eyin naa.

"Ile ti e n ta le fi n yan ara Lodi, ti e n binu sira yin, kin nni anfaani ile naa?, se eyin le ni ile abi Olohun? Ko seni to ra ile ti won sin in sori gbogbo ile naa. Ta lo gbe ile wa lati orun ninu awon baba nla yin? Nitori naa, e wa ona bi e se maa pari ija to wa laarin yin."

Bakan naa lo gba Alaaji Kazeem Ayinla nimoran pe ko gbiyanju lati sagbateru bi won yoo se ko Mosalasi naa pari ko too to asiko odun Ileya, nitori pe oun ko nii pada yoju si won bi won ko ba pari e.

Nigba to n sapejuwe Alaaji Kazeem Ayinla to sagbateru eto idanilekoo naa, o ni Musulumi ododo toun ti mo tipetipe ni, ti ko si gboju soke wo oun loju ri. O ni kawon eeyan wo iwa e lati fi se awokose.

Bee lo tun gbawon Musulumi kaakiri agbaye lamoran pe ki won lo anfaani naa lati te Anobi lasiko aawe yi, ki won si maa saanu fun ara won, paapaa awon ti won ko ni pupo, nitori pe 

Nigba toun naa n soro, Imaamu agba ilu Orinmerunmu, Al-Imam Yaqub Olanrewaju Aro so pe odun 2010 ninwon ti foun je Imaamu agba fun ilu naa ni inu oun dun fun eto yii nitori pe akoko iru e ni, toun si dupe lowo Alaaji Kazeem Ayinla to fi mo Alaaji Semiu White to sagbekale e.

O nigba toun debe loun wo o kuro ni aamo (clay) ti won fi ko o, iyen lodun 2011, to si je pe latigba naa lawon ko tii pari e, tawon si n josin pelu ipo to wa naa.

Imaamu naa so pe gbogbo ipa loun yoo sa lati rii pe awon pari Mosalasi naa pelu iranlowo Alaaji Ayinla, paapaa julo lati ba won gba awon owo tawon eeyan ti won pe jeje e fun won. Bee lo gbadura fun won Alaaji Ayinla ati ileese Seakam Global Resources Limited ati Alaaji Semiu White.

Alaaji Kazeem Ayinla
Ninu oro ti e, Alaaji Kazeem Ayinla so pe ko si nnkan meji to je koun gbe eto naa kale bi ko se lati je ki oju awon araalu naa la sawon nnkan to n mu ifaseyin ba ilu naa, paapaa esin Islam, ki won si le tete se atunse ko too pe ju, idi ni yii toun tun fi gbe agba oniwaasi nni, Sheiki Bello wa lati wa a ba won soro.

O ni ara awon nnkan to ye ki Musulumi ododo maa se niru asiko bayii re e, paapaa pelu awon eko tawon ko ninu esin naa lati kekere, paapaa julo boun tun se wa nipo eni to le gbe iru eto be e kale.

Alaaji Ayinla to so pe bo tile je pe oun kii se omo bibi ilu Orinmerunmu, to je pe ilu Abeokuta loun ti wa, sibe ko si nnkan to di oun lowo lati ma se wa ilosiwaju ilu naa nitori pe ilu naa lo gba oun laaye lati gbe ileese oun kale sibe, toun si n je eere pupo nibe.

O wa a gbawon araalu naa nimoran pe ki won ma se ta awon oro ti Sheiki Ajani Bello ba won so nu, ki won mu gbogbo e lo, ki won si gba alaafia laaye, ki isokan ati ife le joba.

Bee lo seleri pe oun ko nii da iru eto naa duro, to je pe odoodun lawon yoo maa gbe e kale fawon eeyan lati maa je anfaani to po.

Bakan naa lo tun je ko di mi mo pe nnkan to le mu koun je ki ise kiko Mosalasi naa tete ya ni bi Imaamu agba naa atawon Aafa to wa nibi eto naa ba ko gbogbo owo ti won pa sile lai yo ninu e sile, nitori pe otito inu lo se koko ju, bi be e ko, a je pe won ti ri owo ti won fe e fi kun un niyen, nitori pe ise naa kii se owo kekere ni yoo ba a lo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI