Owo olopaa te Spartacus, ogbologbo omo egbe okunkun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, May 8, 2018

Owo olopaa te Spartacus, ogbologbo omo egbe okunkun

Ko seni to gbo bi gendekunrin eni odun metalelogun (23), Gbenga Ogunsanya ti won tun n pe ni Spartacus se n ka boroboro lojo Satide to koja lo lohun logba SARS to wa ni Magbon niluu Abeokuta, ti ko nii mo pe ogbologbo odaran paraku ni, ko da, tawon to gbo bo se n soro si n so pe a fi ki won da ejo iku fun un, pelu bo ti se gba opolopo emi awon eeyan.

Ohun ta a gbo ni pe ojo kejila osu to koja yi lowo olopaa SARS te Spartacus to je olori omo egbe okunkun ti Aye ladugbo Sabo niluu Abeokuta lakoko to tun fe e pa okunrin kan ta a ko tii moruko e dasiko yi.
A gbo pe lati osu kinni odun yi ni awon olopaa ti n wa Spartacus leyin to da wahala nla sile nibi ayeye odun tuntun ti Gomina Ibikunle Amosun maa n sagbateru e lojo kokanlelogbon osu kejila si ojo kinni osu kinni odun tuntun.
Gendekunrin naa ta a gbo pe Oke-Bode lo n gbe tele, sugbon iwa buruku owo e lo je ki won le e danu leyin ti won ni o loo fa ijogbon ladugbo Ago-Oka, nibi ti won ti gun un loju, ko too dip e babalawo kan ti won lo roo lagbara ti gbe e lo toju.
Oogun naa la gbo pe o n gun un, to si bere sii paayan nipakupa, eyi gan an lo gun loo sibi ayeye odun naa lojo naa, to si je bi gomina Amosun se kuro nibe lojo naa, lo bere ti e, to si se opo awon eeyan nijamba.
Spartacus so pe idi toun fi ko oruko sorun ni ti fiimu kan toun wo, to je pe eni to n je oruko naa kii gbo ebe nigba to ba ti n ja, ati pe baba to foun lagbara toun n lo lo so pe ko seni to le ri oun mu, lai mo pe omi si ma a pada wo igbin lenu.
Leyin naa ni Komisana olopaa pase pe kawon olopaa SARS lo wa a wa, sugbon ti won loon a papa bora, ko too dip e asiri e tu si won lowo pelu ore e kan ti won poruko e ni Quam Olubodun, omo ogun odun.
Nigba to n ka boroboro, Spartacus so pe oun kii gbo ebe nigba toun ba ti n fa wahala, toun yoo si rii pe oun gbemi lenu eeyan, ati pe oun ko le kawon eeyan toun ti pa lekun.
Titi di bi e ti n ka iroyin yi lo si fi wa logba SARS , to n gbategun, to si tun fawon olopaa lowo lori bi won yoo se ri awon to ku e mu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI