Owo repete lapo awon araalu Ibadan - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, May 18, 2018

Owo repete lapo awon araalu Ibadan

Gbogbo eto lo ti pari bayii fun ti idanilekoo olojo-kan soso tileese Business Executive International to wa niluu Abeokuta pelu ajosepo ileese Tunkaz Business Enterprises to wa ni Apata niluu Ibadan sagbekale e lojo Satide ola, iyen ojo kejidinlogun osu yi.

Gbongan oja igbalode kan ti won pe ni Kabiyesi Shopping Complex, legbe ileewe girama Adifase (Adifase High School), Ahmadiya, Apata niluu Ibadan ni idanilekoo naa ti fe e waye fawon olugbe ilu Ibadan ati agbegbe e jake-jado laago mewaa aaro.

Gege bi a se gbo, kii se pe awon ileese mejeeji yi deede gbe idanilekoo naa kale fawon eeyan, tabi pe won gbe e kale lati fi pawo wole sapo ara won, ohun ta a gbo ni pe bi eto oro aje orileede yi se ri lo je kawon alase ileese mejeeji yi panupo so pe kawon wa ona lati fi ran awon araalu lowo lori ona ti won yoo maa fi ri owo lai laagun jinna, ko da a, ti ko nii di ise ti won n se tele lowo.

Ofe (free) ni owo iwole, iyen ni pe kii se pe awon to ba fe e kopa ni lati san owo ko too di pe won je anfaani naa, nnkan kan soso tawon akopa ni lati mu dani bi won ba n bo nibi idanilekoo naa ni bairo (biro) ati iwe lati le fi ko nnkan ti won ba gbo sile.

AWIKONKO gbo pe kii se pe awon to kawe nikan ni won n reti nibi idanilekoo naa, awon onise owo, onisowo, osise ijoba tabi aladani, osise feyinti atawon to n reti lati feyinti, ko da, to fi mo awon mekaniiki, aranso (Tailor), aserunloge (hairdresser) ati bee bee lo ni won ni anfaani lati kopa.

Gege bi a se mo pe ona kan ko w'oja, ti ise kan ko too gbo bukata ara eni mo, eyi lo fa a idanilekoo yi lati ran awon araalu lowo.

Bo tile je pe orisirisi idanilekoo lopo awon eeyan n gbe kale, to si je pe ona lati fi wa owo ni won n wa, sugbon AWIKONKO fi n da a yin loju pe ko seni ti yoo kopa nibi idanilekoo yii, ti yoo so pe oun padanu asiko e, nitori pe opo awon ti won ti n kopa nibi idanilekoo tawon ileese mejeeji yi n sagbateru e ni won n jeri sii pe ileese to se e fokan-tan ni won.

Pupo ninu awon to wa nibi idanilekoo ti won se niluu Abeokuta lai pe yi ni won n kan saara si won pe ise ni won n se, tawon eeyan si ti n je anfaani repete lori eko ti won ko nibe, eyi gan an lo fa a tawon akopa ti won wa lati ona to jin fi so pe ki won gbe e wa siluu awon, kawon ti won ko ni anfaani lati wa sibe naa le je iru anfaani yii.

Fun alaye lekunrere, tabi lati to o yin s’ona, e le kan si awon nomba yi 07065407593, 08138426960

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI