Alaga ile igbimo to n ri soro awon agbegbe lorileede Naijiria, Onarebu Oladipupo Adebutu ti seleri igbe aye irorun fawon odo orileede yi, paapaa awon odo ipinle Ogun bi won ba fibo gbe e wole gege bi gomina ipinle Ogun lodun 2019.
Onarebu Adebutu to n soju ekun Remo nile igbimo asoju-sofin niluu Abuja lo soro yi lai pe nibi to ti fi ero amunawa tiransifoma (transformer) ta awon agbegbe bii Iwoye-Ketu, Obada ati Idofa lore lose to koja.
Adebutu ni pelu ipa toun atawon ebi oun ti ko nipa idagbasoke ati ilosiwaju orileede yi, paapaa ipinle Ogun, iyen awon ipa ti ko le pare ninu iwe itan, sibe oun ko nii dawo duro lati maa tesiwaju.
O ni boun ba fi le wole gege bi gomina ipinle Ogun, awon odo ti bo sinu igbadun ayeraye, bee lawon oja naa yoo maa yi ninu ola, paapaa toun yoo tun so eko di ofe fawon omo ileeko alakobere, ti owo ileewe awon fasiti naa yoo tun ja wale kaakiri ipinle naa.
Gbajumo oloselu omo egbe PDP naa, to n gbero lati jade dupo gomina lodun 2019 tun so siwaju sii pe awon eeyan yoo lanfaani lati maa ri anfaani eto eyawo je fun ti okoowo won, ti gbogbo eeyan yoo si maa ri ise se, towo yoo si maa wa lowo won ni gbogbo igba.
Bakan naa lo wa gbawon odo lamoran pe ki won yago patapata ninu awon iwa adojutini, eyi ti ko ye omoluabi lawujo. O lawon iwa bii lilu jibiti lori ero ayelujara (Yahoo-yahoo), ise asewo, egbe okunkun, iwa ipa ati bee bee lo lo n tete mu iparun ba awon odo lasiko yi, ti won si gbodo yera fun bi won ba fe e pe laye.
Nigba to n soro nipa ero amunawa tiransifoma (transformer) to fun awon ilu naa, LADO ni lati le mu won kuro ninu okunkun ti won ti wa lati odun pipe ni, ki won si bo sinu imole bii tawon ilu to ti laju min in.
Lara awon to wa nibi eto naa ni: Ooye tiluu Iwoye Ketu, Oba Joel Ademola; Adele Baale ilu Obada, Oloye Saliu Suberu; alaga adugbo (CDA) Idofa, Oloye Gabriel Akinwunmi ati Onarebu Seye Sonuga.
No comments:
Post a Comment