Iyaale ile fe e ko oko e sile - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, June 20, 2018

Iyaale ile fe e ko oko e sile


Emi ko ni mo lawon omo, e tu wa ka - Ibrahim

Bi Baale ile kan tojo ori e ko tii ju odun kokandinlogun (19) ko ba tete yi ohun e pada pe oun loun lawon omo mejo tiyawo e bi fun un, afaimo ko ma pada ba ara e nibi ti ko fe, tabi ko ba wahala ojo iwaju pade.

Lose to koja yi ni iyaale ile kan, Ayisat Olayinka Ayelotan mu ejo lo sile ejo koko-koko to wa ni Ake niluu Abeokuta pe ki won ba oun tu igbeyawo to wa laarin oun ati Ibrahim Ayelotan ka nitori to n fojoojumo da oun laamu ninu ile, to si n so pe oun ko loun lawon omo meji toun bi fun un.

Ayisat be ile ejo pe yato si pe won tu awon mejeeji ka, ki won je ki oko oun towo bo iwe adehun pe ko ni omo kankan lodo oun lojo iwaju ati titi ti aye maa fi pare lawon ko je ara won ni omo, toun yoo si tiraka lati toju awon omo naa funra oun.

Nigba to n soro, Ibrahim so pe looto loun so pe oun ko loun lawon omo naa, iyen Yetunde ati Rokeeb toun si duro lori oro oun nibikibi, ati pe oun setan lati towo bowe lori e. O ni ko si nnkan meji to je koun so be e ni awon oro tiyawo oun maa n so pe to ba ya awon omo a mo baba won.

O ni Musulumi loun, toun si so awon omo naa loruko Musulumi, sugbon iyawo oun kii gba ki won lo sile keu lati loo ko eko nipa esin Islam, toun ba si soro, se lo maa ta mo oun lorun, to maa so oun also mu.

Ibrahim so pe Ayisat kii gba ki awon omo oun lo si odo ebi oun, depodepo wi pe yoo je ki won gba nnkan je lowo iya oun tabi iya-iya oun, nitori pe kii foju sile fenikeni ninu molebi oun.

O tun niyalenu lo maa n je foun nigba toun baa n ri Ayisat ninu ile okunrin kan to n gbe nitosi ile awon, ati pe bi oro ba se bi oro laarin won, odo okunrin naa ti ko niyawo nile lo maa n lo sun.

Nigba tawon mejeeji n soro, Aare ile ejo naa, Oloye Akande O. O ati igbakeji e, Onorebu Arabinrin Majekodunmi H. I so pe ko si nnkan to kan awon nipa igbeyawo won, boya won si fe maa fe ara won, ti won ni kawon tu won ka, sugbon eyi to kan awon ju ni ti oro omo.

Oloye Akande ni ki Ibrahim loo ro oro to n so daadaa ko too di ojoTusde ola, iyen ojo kokandinlogun (19) osu kefa, ko si tun erongba e pa lori awon omo naa nitori pe kii se owo kekere lo maa na to ba maa towo bowe, nitori pe awon yoo tare e si osibitu ti yoo ti se ayewo eje, iyen DNA test.

Won je ko ye e pe bi ayewo eje awon omo mejeeji ba fi le jo ti e, ewon ni yoo gbeyin si nitori esun odaran ninwon yoo fi kan an, ati pe bi wahala ojo iwaju ba de, o le ma le ko ara e yo gege bi iriri tawon ti ri.


No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI