AMOSUN TI FI IWA ODARAN E GBAGBE AWON EKA TO PO NIPINLE OGUN - SIKIRULAI OGUNDELE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, June 1, 2018

AMOSUN TI FI IWA ODARAN E GBAGBE AWON EKA TO PO NIPINLE OGUN - SIKIRULAI OGUNDELE


...Bee ni Adebutu seleri eto ilera to peye fawon araalu


Tutu Aworinde


Alaga egbe oselu PDP nipinle Ogun, Onarebu Sikirulai Ogundele ti bu enu ate lu isejoba gomina Ibikunle Amosun tipinle naa latari awon ona to so pe o n gba se ijoba e, paapaa lori awon biriiji to so pe oun nikan lo doju ko.


Ogundele lo soro yi lonii ojo kinni osu kefa nibi ipade ti Onarebu Oladipupo Adebutu se pelu awon osise eleto ilera kaakiri ipinle Ogun, ti won se ninu okan lara awon gbongan ayeye ti Park Inn to wa ni Kuto, Abeokuta.

Gege b'AWIKONKO se gbo, pataki eto naa ni lati so awon isoro ati adojuko to koju eka eto ilera, eyi to n mu ifaseyin ba gbogbo ileese eleto ilera kaakiri ipinle ati bi Onarebu Adebutu se le bawon wa iyanju sii.

"Inu mi dun lati wa niwaju lonii lati soro, e ma binu pe maa fi oselu si oro ti mo fe e so. PDP ni egbe oselu wa, ti a si ni aami idanimo Onarebu Adebutu o si ti se daadaa sinu egbe wa lona ti a ko le maa so tan.

"Mo ni anfaani lati so fun un yin lonii pe egbe naa je egbe to n se ojuse e ni gbogbo igba. A ti anfaani lati se ijoba leemeji otooto, ko si ariyanjiyan ninu e pe ijoba to wa lori aleefa lowo nipinle Ogun ti je opolopo itiju fawon araalu, nitori pe o ti ja won kule gan.

"O ti fi iwa odaran e gbagbe gbogbo eka to ku patapata nipinle Ogun. Mo fe e tun un so leekan sii, o ti fi iwa odaran owo e pa gbogbo eka ijoba to ku patapata, to je pe biriiji ati ona lo doju ko.

"Idi ni pe ko seni yo le se akosile owo ti won fi se ona, paapaa biriiji. Ona ti won si fi n ko owo je, ti won fi n ko owo sapo ara won niyen. Mo so fun un yin pe maa mu oselu wo inu oro mi.

"Ka too yan Onarebu Adebutu gege bi eni ti yoo dije dupo, a ti wo awon nnkan amuye lara e, a si ti rii pe k kaju osuwon."


Nigba to n soro, Onarebu Oladipupo Adebutu dupe lowo awon osise eleto ilera naa fun bi won se wa a ba a sepade, to si seleri fun won pe oun yoo rojo owo si eka eto ilera boun ba wole.

Adebutu loun mo pe eka eto ilera nipinle Ogun ti denu kole patapata, to si je pe ojoojumo ni Gomina Amosun n so pe oun n ko owo sibe, sugbon to je pe iro nla banta-banta lo n pa.

Onarebu naa to n soju ekun Remo nile igbimo asofin kekere niluu Abuja ni ko seni to so pe ki Gomina Amosun ma se ona ati biriiji, sugbon iyen ko so pe ko wa a gbagbe awon eka ileese ijoba to ku, paapaa bii eka eto eko, eto ilera ati beebeelo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI