KO SI NNKAN TO BURU NINU KI MUSULUMI ATI KIRISITEENI BA ARA WON JEUN - WOLII SANYAOLU - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Monday, June 4, 2018

KO SI NNKAN TO BURU NINU KI MUSULUMI ATI KIRISITEENI BA ARA WON JEUN - WOLII SANYAOLU

Biodun Sanyaolu

Agba ojise Olorun nni, ti ijo The Eternal Sacred Order of the Cherubim and Seraphim to wa ni agbegbe Surulere, Ima niluu Abeokuta, Apositoli Agba, Biodun Sanyaolu ti so pe ko si nnkan to buru ninu ki awon elesin Musulumi ati Kirisiteeni maa ba ara won je papo ninu awo kan naa.

Wolii Sanyaolu to tun je alakoso agba fun oro eko, odo ati idagbasoke awon obinrin (National Director, Education, Youth and Women Development) lo soro naa lojo Sande to koja yi lakoko to n waasu nibi eto ayeye idupe olodoodun ti ijo naa, akoko iru e.

Isin Ajodun idupe naa ni won pe akori e ni Bo Se Dun To Ki Awon Ara Maa Gbe Ninu Isokan "How Good And Pleasant Brothers Live Together In Unity" (Psalms 113:1), ni won ti gba orisirisi alejo awon omo ijo naa kaakiri agbaye, paapaa awon to wa nipinle Ogun.

Awon to gba awoodu
Sanyaolu so pe laye atijo, to ba ti n di iru asiko bayii, iyen asiko aawe Ramadaani tawon Musulumi ba ti n gba aawe won, inu awon Kirisiteeni yoo ti maa dun pe ki won tete pari e, nitori pe ki won le je ounje odun, sugbon aini ife ti yi gbogbo e pada lasiko ta a wa yi, eyi gan an lo fa owo aago ilosiwaju ati idagbasoke orileede Naijiria seyin.

O ni bee naa lo ri bi asiko keresimesi ba de, ti awon Musulumi naa yoo maa reti ounje lati odo Kirisiteeni, ko da a ti won ko ba gbe ounje naa lo fun won, awon gan an tun loo beere pe ounje awon n ko.

Ojise Olorun naa ni, kii se pe awon eeyan ko ni se ara won, nitori pe awon ibeji ti won bi lojo kan naa ko le ni iwa kan naa, sugbon ti a gbodo dariji ara wa lesekese lati le mu ki alaafia joba.

Nigba to n so awon ona ti a le gba lati ni irepo, ki a si tun wa ni isokan, Wolii Sanyaolu je ko di mi mo pe; a gbodo gba pe okan soso ni wa, a gbodo gba fun ara wa, a gbodo maa wa alaafia ki a si tun maa lepa e, a gbodo ni ife to ye kooro si ara wa, a gbodo bowo ki a si ni suuru fun ara wa, a gbodo maa sa fun nnkan to le mu ka se ara wa.

Bakan naa lo menuba die lara awon nnkan to n fa aini irepo, o ni; igberaga ati ofekufe, aini emi mimo, ikorira eni, ilara, owu, gbigbe ebi fun alare, abinu ati irunu, etaanu.

O ni Olorun kii gbe nibi ti rudurudu ba ti n joba, agbegbe ti alaafia ba wa nikan Olorun n gbe, nitori naa lo se dara fun Enitan lati maa gbe ni irepo ni gbogbo igba.

"Isokan nikan ni ohun amuye to le mu ijo ati orileede lapapo lo siwaju. Nigba ti a ba wa ni isokan, ti a ko maa gbe ikorira kaakiri okan wa si ara wa, nigba ti a ba nife enikeji wa gege bi ara wa, nigba ti a ba n ka ara wa kun."

Lakotan nigba to n gba ijoba Aare Muhammadu Buhari lamoran, o ni ko boju wo iya tawon araalu n je lasiko yi ko fi se awon ohun amuye to le mu kawon eeyan je mudunmudun eto oselu awaarawa, ko si fi erin sawon araalu ni ereke.

Ninu oro ti e, Alagba Titus Oladele Alalade to je alaga ijo naa (Provincial Chairman) so bo tile je pe yoo soro lati je ki awon ijo alaso funfun ti Mose Orimolade da sile nitori ipo, sibe alaafia, irepo ati isokan lo se pataki, oun nikan si ni ona abayo.

O gbawon omo orileede yi, paapaa awon omo ijo naa kaakiri lamoran ki won maa lepa alaafia lati joba laarin ara won, ki won si nife ara won nitori pe ife nikan lo se pataki.

AWIKONKO gbo pe won tun lo anfaani ayeye isin idupe naa lati fi fun awon to ti sise takuntakun ni ami eye idalola, iyen awon bii Olu Orenuga; Biodun Sanyaolu; A. O Soremi; Lanre Folarin ati S. L Akinsanya.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI