Awon Araalu N Gbe Awon Olopaa SARS S'epe l'Abeokuta Nitori Tisa Ti Won Yinbon Fun - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, June 27, 2018

Awon Araalu N Gbe Awon Olopaa SARS S'epe l'Abeokuta Nitori Tisa Ti Won Yinbon Fun

Titi di bi e ti n ka iroyin yi, epe rabande-rabande lawon araalu n gbe awon olopaa SARS se latari bi won se yinbon fun okan lara awon osise ijoba to je tisa ileewe girama kan ta a ko tii moruko e dasiko yii.


O po awon ti won si gbo soro naa ni won n bu enu ate lu ileese olopaa kaakiri, paapaa ileese olopaa ipinle Ogun labe Komisana won, Ahmed Iliyasu latari bi won ko se towo omo awon SARS won bo aso, ati pe awon araalu ni won ni ki won maa daabo bo, kii se pe ki won maa koju ija si won.

Lose to lo lohun, iyen ojo kejila osu yii la gbo pe awon olopaa SARS loo dena de okunrin kan to n lo jeje e, ti won si n ba okunrin naa fa wahala, nitori ti won ro pe omo Yahoo ni, ti won si fe e gba owo lowo e, iyen labe biriiji Ibara to wa niluu Abeokuta.


Gege b'AWIKONKO se gbo, nibi ti won ti n fa oro naa la gbo pe awon eeyan to wa layika ti lo sibe lati da sii, sugbon tawon SARS bere sii fibon hale mo awon eeyan naa.

Igba to di pe awon ero ti pe le won lori la gbo awon SARS so oro kekere naa di nla mo awon eeyan lowo, to si mu ki won bere sii yinbon soke lati je kawon eeyan naa salo kuro lodo won.


AWIKONKO gbo pe igba tawon ti won ni emi won lo ti owo tawon SARS naa gbe nipa ibon ti won da bole lo mu k'onikaluku won tete bere sii ba ese won soro.

Won ni eyi lo mu kawon kan gba oro naa si odi, to si mu ki won bere sii ju okuta lu awon olopaa SARS naa lati le dawo ibon ti won n yin duro.


Nibe la gbo pe odomokunrin kan toro naa soju e ti ki foonu e mole, to si bere sii ya awonran nnkan to n sele, eyi lo fa a ti won ni okan lara awon SARS to rii ti sare loo ba a, to si bere sii gba a leti, to tun gba foonu e.

Bawon eeyan naa se n ba ese won soro gege b'AWIKONKO se gbo ni won so pe se ni okan lara awon SARS yi ti loo ba Tisa kan, Ogbeni Ola Hammed toun n koja lo jeje e lai mo nnkan to n sele, to si bere sii luu.

Ohun ta a gbo ni pe gbogbo bi won se so pe Hammed n fi ara e han gege bi osise ijoba, ati pe jeje oun loun n lo ni won ni ko wo SARS naa leti, afigba to ki ibon mole, to si yin in fun un lese.


Bi ibon yi se ba Hammed lese la gbo pe awon olopaa SARS naa ti na papa bora, tawon eeyan si bere sii gbe won s'epe nla-nla. Nibe la gbo pe awon eleyinju aanu ti sare gbe Hammed lo si osibitu aladani kan to wa ni Onikolobo, iyen Korede fun itoju.

Igba tawon osise osibitu Korede yii se itoju die ti won si rii pe agbara won ko ka ni won tare e si osibitu ijoba, iyen Jenera to wa ni Ijaye. Bo tile je pe awon osise osibitu naa ko koko fe e tewo gba Hammed latari iwe eri lati odo awon olopaa ti won n beere lowo e.

Sugbon alaye ati ebe to po gege boun naa tun se je osise ijoba lo mu ki won gba oro e ye wo nigba ti won rii pe irora to n je ti fe e gba emi e.


Nnkan to n kan awon eeyan lominu pupo ni bi won se so pe kaka ki alukoro olopaa ipinle Ogun, Abimbola Oyeyemi da si oro naa, ko si se nnkan to ye, se loo gba ori redio lo leyin ojo kerin tisele naa sele, to si loo n so pe awon araalu ni won koko loo so okuta lu awon olopaa SARS naa, to fi di pe awon yen bere sii yinbon soke lati gba ara won sile, ki won ma baa se won lese.


Nigba to n fedun okan e han, to si n be ijoba ipinle Ogun lati da si oro naa, ki won si fowo ofin muu, Hammed ninu oro to ko sori ero ayelujara lo ti so pe gege bi osise ijoba, ijoba ni lati dide iranlowo foun ki won si tun le tete gba awon araalu ti won ko mo nnkan kan sile lowo awon olopaa SARS yi ko too di pe won pa won tan.

Fawon to ba n ka Iroyin AWIKONKO daadaa, won a mo pe lai pe yi la gbe iroyin kan jade pe awon olopaa SARS le Awilo pa l'Abeokuta, isele yi lo sele ti won lawon olopaa SARS pada loo gbesan, ti won tun n wa awon omo Yahoo, ko too di pe Awilo naa loo fi aya lu irin, to si ku leyin ojo keta.

Gbogbo akitiyan lati ba agbenuso olopaa, Abimbola Oyeyemi soro lori aago lo ja si pabo titi ta a fi sakojopo iroyin yi tan, nitori ta a pe foonu e, 08123822**0 ti ko lo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI