IDIBO GOMINA: Awon Ibo Lawon Setan Lati Satileyin Fun Seneto Yayi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, June 27, 2018

IDIBO GOMINA: Awon Ibo Lawon Setan Lati Satileyin Fun Seneto Yayi

Egbe awon Ibo nipinle Ogun, Aka Bu Eze Ndigbo to wa niluu Ado Odo-Ota, Ado-Igbesa lawon ti setan lati satileyin fun Seneto Solomon Olamilekan Adeola to n soju ekun Lagos West nile igbimo asofin agba niluu Abuja, iyen to ba di asiko lati dibo gomina ipinle Ogun lodun 2019.


Be o ba gbagbe, Seneto Adeola tawon eeyan tun mo si Yayi lo fe e gbapoti gege bi adije sipo gomina labe egbe oselu APC, iyen ninu idibo to n bo lona, ti gbogbo eto ipolongo idibo naa ko ni pe e bere ni pereu bi ajo INEC ba ti kede sita.

Lai pe yi ni alaga egbe naa, Ogbeni James Ikechukwu Ijeoma je jo di mi mo lasiko ti okan lara awon to fe e dije dupo omo ile igbimo asoju-sofin nipinle Ogun, Onarebu Sunmonu Segun loo sabewo si won ni ile itura kan ta a foruko bo lasiri, eyi to wa loju ona Alapoti si Lusada.

Ogbeni Ijeoma so pe egbe awon ko si fun adije meji, bi ko se fun Seneto Yayi, tawon ko si tii setan lati pada leyin e pelu bo se n fowosowopo pelu won, to si tun n satileyin fun won.

Alaga naa je ko di mi mo pe kii se pe awon sese fe e tele Yayi nitori pe awon ti jo wa lati ojo to ti pe, ilu Eko lawon si ti bere nigba tawon yoo bere, tawon yoo si tun lo gbogbo agbara ati ipa ti won ni lati rii pe Seneto kukuru naa depo gomina lodun 2019.

O wa a tenumo on pe isoro kan soso tawon ni lagbegbe naa ni ti ona won ti ko dara rara, to je pe agidi ni moto fi n rin nibe, toun si n fe ki Seneto Yayi bawon da sii pelu ipo e gege bi Seneto, iyen bi won ba gba a laaye, nitori pe awon gomina to ti se tele ati eyi to.wa lori oye lowolowo ni won ti wa a seleri fawon sugbon ti won ko mu ileri won se titi dasiko yii.

Nigba toun naa n soro, Onarebu Sunmonu Segun dupe lowo egbe awon Ibo naa pelu bi won se gba a laaye lati bawon sepade po, ati ileri ti won se lati satileyin fun Yayi.

O wa a gba won nimoran pe ki tete loo gba kaadi idibo alalope (PVC) won ki asiko too lo, nitori pe ona kan soso to le je ki ibo won di kika ni ki won gba kaadi idibo naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI