E GBA MI LOWO BUHARI TO FE E TI MI MOLE O - OBASANJO PARIWO SITA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, June 8, 2018

E GBA MI LOWO BUHARI TO FE E TI MI MOLE O - OBASANJO PARIWO SITA

Oloye Olusegun Obasanjo to je Aare teleri lorileede Naijiria ti pariwo sita losan ojo onii Fraide pe kawon eeyan gba oun lowo Aare Muhammadu Buhari pelu bo se n gbiyanju lati wo oun gbuurugbu lo sodo ajo EFCC to n gbogun ti iwa ajebanu, pelu erongba lati ti oun mole.

Buhari ati Obasanjo
Ninu atejade ti Ogbeni Kehinde Akinyemi to je alakoso iroyin e gbe jade losan onii pe Aare Buhari n gbiyanju lati pa iro nla banta-banta moun pelu iranlowo awon eleri eke pe oun lowo si iwa ibaje.

Be o ba gbagbe ninu osu kinni odun yi ni Oloye Olusegun Obasanjo gbe atejade kan jade lati fi bu enu ate isejoba Buhari, ati pe ko tete gbe igbese lati wa iyanju si awon isoro to n doju ko orileede yi.

Eyi gan an la gbo pe o fa a to ni Aare Buhari fe e gbe igbimo dide lati se iwadii ijoba saa Obasanjo, eyi to so pe o fe e paro moun lati gbe oun pamo si ahamo awon EFCC, ti asiri naa si ti tu soun lowo.

Baba naa so pe Buhari tun ti pari awon ayederu iwe kan pelu awon ayederu seleri lati fi tako oun, paapaa fun ti saa isakojo Oloogbe Jenera Sanni Abacha toun je okan lara awon to ba a sise.

Ebora Owu so pe asiri naa ti tu soun lowo pe Buhari ti n wa gbogbo ona lati mu oun, ti emi oun ko si labe aabo mo, ati pe ko si iye idunkoko ti Buhari le se moun, to le mu koun bo enu lati so iru eeyan ti Buhari je.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI