IJEBU NI GOMINA KAN NIPINLE OGUN, KII SE YEWA - OGUNBANJO - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, June 8, 2018

IJEBU NI GOMINA KAN NIPINLE OGUN, KII SE YEWA - OGUNBANJO

Okan lara awon to fee jade dupo gomina ipinle Ogun labe egbe oselu Alliance for New Nigeria, ANN, Ogbeni Ademola Ogunbanjo so pe etanje lati da oselu ipinle Ogun ru ni iroyin ti won n gbe kaakiri pe awon kan ni ipo gomina kan, awon kan ko lo kan.

Ademola Ogunbanjo
Ademola Ogunbanjo lo soro yi laaro oni lakoko to n fi ara han awon oniroyin nipinle Ogun gege bi eni to fe e jade dupo gomina ipinle Ogun labe egbe oselu ANN ninu idibo odun 2019.

Nibe lo ti so pe looto ni won n gbe iroyin kaakiri pe awon eya Yewa lo kan lati di gomina ipinle naa lodun 2019, sugbon ti iroyin naa je etanje lati dabaru eto oselu ipinle Ogun, ati lati si awon araalu lokan.

Omo bibi Odo Botu niluu Ijebu-Igbo naa so pe nigba ti won maa koko da ipinle Ogun sile lodun 1976, omo Ijebu ni, iyen Oloogbe Olabisi Onabanjo, nigba ti won si maa yan gomina keji, omo Egba ni, Oloye Olusegun Osoba, leyin naa ni ijebu tun gbajoba, iyen Otunba Gbenga Daniel ko to wa a di pe Gomina Amosun toun je omo Egba depo naa.

Ademola ni ko tii to asiko ti won yoo bere sii pin ipo gomina ipinle Ogun fun awon eya Yewa nitori pe won ko si ninu akosile awon ti yoo je gomina ipinle naa, nitori naa, ki won si loo gbagbe ipo naa lasiko yi.

Nigba to n so erongba e lati jade dupo gomina lodun 2019, Ogbeni Ademola Ogunbanjo so pe kii se pe oun n wa ipo, agbara tabi anfaani, bi ko se itara toun ni lati da ogo orileede Naijiria to ti sonu pada, eyi toun fe e bere lati ipinle Ogun toun ti wa.

Okunrin omodun merinlelogoji (44) naa ni bo tile je pe oun kii se oloselu, ti ofin orileede yi ko si faaye gba enikeni lati jade dupo lai si labe egbe oselu kan, eyi lo fa a toun fi fe e gba egbe oselu tuntun naa, iyen ANN jade fun ti idibo to n bo naa.

Bakan naa lo tenu mon on pe aimoye ohun amusoro nipinle Ogun ni, sugbon tawon ijoba to ti n de ori aleefa kii gboju sibe lati fi mu owo wole sapo won, kawon araalun si le maa je anfaani e lojoojumo.

O ni awon nnkan bii Koko (Cocoa) si wa nipinle, Bitumen, Limestone atawon nnkan min in ni Olorun fi ta ipinle Ogun lore, ti ko si sijoba to mu idagbasoke bawon nnkan naa, sugbon bi oun ba fi le wole gege bi gomina, gbogbo nnkan naa loun yoo pada gbe dide.

Bee lo so pe asiko toun yoo tu awon araalu lara nitori pe ko si eni ti yoo ji lojo kan ti ko nii mo nnkan to kan lati se ti yoo mu owo wole fun in lojumo, ti yoo si tun maa je ounje eemeta lojumo.

O ni asiko re e fawon araalu lati je mudunmudun eto oselu awaarawa ti a ti n pariwo lati ojo pipe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI