Okan pataki lara awon omo egbe oselu APC nipinle Ogun, Komureedi Rasheed Aroboto ti pariwo sita pe oun ko kuro legbe oselu APC rara, aheso lasan ni won n gbe kaakiri lati fi ba oun loruko je, ti ko si ye ko ri bee.
Komureedi Aroboto, eni to tun je okan lara awon omo egbe oselu naa ti Gomina Ibikunle Amosun feran ju lo pariwo yi sita lai pe yi lakoko to n b'AWIKONKO soro lori foonu lati tako iroyin eleje to n kaakiri nipa e.
O ni ko si iro ninu iroyin eleje naa, ise awon ota atawon alatako ti won fe e ba toun je lodo Gomina Amosun ni, nitori pe gbogbo ona ni won n gba lati le oun kuro ninu egbe, toun ko si nii gba fun won.
Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo se so, won ni se ni okunrin naa, iyen Aroboto loo darapo mo egbe awon odo oloselu kan ti won pe ni Ogun State Youth Agenda, koda, ti won tun fi je adari egbe naa nipinle Ogun.
Eyi lo fa a ti won ni awon kan ti ko gba ti e ninu egbe oselu APC fi n gbe e kaakiri pe egbe oselu ni egbe awon odo naa lati ja fawon odo pe ki won jade dupo gege bii pe asiko awon odo la wa yi.
Bee la tun gbo pe se lawon eeyan naa tun n so pe nitori pe won ko mu Komureedi Aroboto gege bi olori awon odo legbe oselu APC naa lo je ko fegbe naa sile, koda, ti won tun ni se lo ko pupo ninu awon to gba tie legbe APC kuro ninu egbe lo sinu egbe oselu min in.
Ninu oro Komureedi Rasheed Aroboto, o so pe "Aheso nla patapata to jinna si otito ni won n so pe emi gege bi enikan kuro legbe oselu APC nitori pe omo egbe si ni mi, mo si tun je omo egbe Gomina Ibikunle Amosun tokan-tokan.
"Eni to n soro yi kaakiri kan se e nipa ife ara e ni, ati pe won le fipa mu Esin lo s'odo, won ko le fipa fun un l'omi mu. Egbe oselu APC, egbe mi ni, mo si je alatileyin fun Gomina Amosun nitori pe oga mi ni, olori mi si ni.
"Bo tile je pe OSYA je egbe to n fe ilosiwaju awon odo lai ya egbe oselu kankan s'oto, gbogbo awon odo to wa lawon egbe oselu kaakiri ni won letoo lati darapo mo egbe OSYA yi.
"Gege bi eni akoko ti mo je legbe OSYA, omo egbe APC ni mi, gbogbo awon eto to ye ki n kopa ninu egbe ni mo n ko nipinle Ogun ati agbegbe e kaakiri.
"Mo wa n fi asiko yi so fun pe gbogbo omo ipinle Ogun, yi mo si n so fun gbogbo awon eeyan pe ki won gba se gbo oro awon elegan wipe emi Komureedi Rasheed Aroboto fi egbe oselu APC sile lo sinu egbe min in."
No comments:
Post a Comment