Idije Russia 2018: Mikel Seleri Fawon Omo Naijiria - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 21, 2018

Idije Russia 2018: Mikel Seleri Fawon Omo Naijiria

Balogun iko egbe agbaboolu orileede Naijiria, Super Eagles, iyen John Mikel Obi ti fokan awon omo orileede yi bale pe nnkan to ba gba loun maa fun un lati rii pe awon jawe olubori ninu ifigagbaga pelu egbe agbaboolu orileede Iceland lojo Fraide to n bo yii.


Mikel lo seleri yi losan onii Wesde pe oun setan lati fi ipo oun gege bi balogun iko egbe agbaboolu naa dii lati rii pe awon feyin egbe alatako won gbole, kawon si le ni anfaani lati de ipele to joju ninu idije ife eye agbaye ti Russia 2018 to n lo lowo.

Ori ero ayelujara, iyen Twitter loro naa ti jade nigba ti egbe agbaboolu Super Eagles fi oro naa sita pe Mikel ti seleri lati lo gbogbo agbara ati ipo e rii pe won jawe olubori.

Bi oro yi si ti se jade sita lawon ololufe egbe agbaboolu naa ti bere sii so orisirisi oro, bawon kan se n sadura fun won, bee lawon kan n gbawon nimonran pe ki won mura sile daadaa nitori pe adura nikan ko le se e, bi ko se pe ki won sa gbogbo agbara won.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI