Asiri Awon Onise Ibi Tu L'Abuja, E Woju Won O - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, June 20, 2018

Asiri Awon Onise Ibi Tu L'Abuja, E Woju Won O

Lose to koja yi nileese olopaa ipinle FCT, Abuja foju awon odaran han fawon oniroyin, nibe naa ni won ti foju awon agbenipa meji kan, Chukwujekwu Ezeugo ati Emmanuel Adogah ti won fesun kan pe won ji Arabinrin Charity Aiyedogbon gbe, ti won si ti pa a danu.


Gege b'AWIKONKO se gbo, won ni ninu osu karun odun 2016 ni won ti ji Charity gbe lagbegbe Kagini, niluu Abuja, iyen lojo kesan an, latigba naa la gbo pe won ti n wa obinrin naa atawon to kii gbe.

Nigba tasiri won maa tu, Ezeugo to je omodun metadinlogbon (27) ni won lasiri e koto tu sawon olopaa lowo niluu Benin, oun lo si satona bi won se ri oga e, Adogah toun je omodun mejidinlogbon (28) mu niluu Abuja lojo kokanla osu yi.

Omo bibi ilu Enugu ni won pe Ezeugo nigba ti Adogah je omo ipinle Edo.

AWIKONKO gbo pe Ezeugo n ba Charity dore ikoko, ko too di pe won nija kekere kan sele laarin won, eyi lo fa ti won ni Ezeugo fi ranse pe Adogah pe kawon jo pa Charity leyin to roo ni oti yo tan.


Leyin ti won loo ro Charity loti yo lo ba gbe e kuro nile lagbegbe Yaounde lo si agbegbe Kagini, nibi ti won pa a si, ti won si tun ge oku e si welewele, ko too di oe won gbe e sinu apo loo ju si segbe banki kan ni Ushafa, Bwari, Abuja.

A gbo pe idi ti won fi pa Charity ni pe won fe e gba gbogbo ogun e to ni, to fi mo moto e, Acura to je jiipu, sugbon ti won lawon olopaa ti gba lowo won bayii.

Nigba to n soro, Ogbeni Sadiq Bello to je Komisana olopaa niluu Abuja so pe awon odaran naa yoo foju bale ejo lai pe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI