Nitori Abiola; Onarebu Kayode Oladipupo Gboriyin Fun Buhari - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, June 8, 2018

Nitori Abiola; Onarebu Kayode Oladipupo Gboriyin Fun Buhari

Okan lara awon to n foju sona lati jade dupo omo ile igbimo asoju-sofin nipinle Ogun, Onarebu Kayode Oladipupo ti gboriyin fun Aare orileede Naijiria, Muhammadu Buhari latari bo se so pe Oloogbe Moshood Kashimawo Abiola lo jawe olubori idibo odun 1993, ati pe gbogbo ojo kejila osu kefa ni yoo je ojo ayajo eto oselu awaarawa.

Onarebu Kayode
Be o ba gbagbe, lojo Wesde to koja yi Aare Buhari so ninu atejade kan pe ko nii si ise lojo Tusde tonn bo tii se ojo kejila osu kefa lati le bu ola fun oloogbe MKO Abiola topo awon eeyan gba pe oun lo jawe olubori idibo Aare todun 1993.

Idibo odun 1993 naa pelu bo se soju saara to, tawon eeyan si ti n ki MKO Abiola ku oriire ni Jenera Ibrahim Babangida to je Aare orileede yi labe ologun nigba naa danu pe MKO se nnkan to tako ofin idibo pelu bo se wo aso egbe oselu SDP loo dibo.

Onarebu Kayode Oladipupo ninu atejade to fi sowo si AWIKONKO lai pe yi lo ti so pe Buhari ye leni tawon araalu gbodo gbe osuba kare fun pelu ase to sese gbe kale naa lati yi ayajo ojo  oselu awaarawa kuro lojo kokandinlogbon osu karun (May 29) si ojo kejila osu kefa (June 12).

Siwaju sii lo tun so pe asiko bo tile je pe opo awon omo orileede yi ati kaakiri agbaye ni won ti n foju sona fun iru agbekale bayii, sibe asiko ti Aare Buhari pase yi yoo je kawon eeyan mo iriri Buhari daadaa, ti oruko e ko si le pare ninu iwe itan.

Bakan naa lo gba ajo eleto idibo INEC lamoran pe ki won gbe esi idibo odun 1993 naa to gbe Abiola wole jade sita fawon eeyan lati mo iye idibo to gbe e wole.

Bee lo tun gba ijoba lamoran pe ki won tete se awon eto to ba to si awon Aare teleri lorileede yi fun ebi oloogbe Abiola, nitori pe eyi gan an lo maa fokan awon araalu bale lori ipinu tuntun naa.

Onarebu Kayode Oladipupo ti gbe apoti kanselo l'Abeokuta South, Ward 2 labe egbe oselu UPN lodun 2015, ni bayii, ile igbimo asofin ipinle Ogun lo n lo lodun 2019 lati loo soju Abeokuta South Constituency 1 labe egbe oselu ACCORD.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI