O Tan O: Obasanjo Ati Bode George Di Ore Apapandodo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 23, 2018

O Tan O: Obasanjo Ati Bode George Di Ore Apapandodo

Bo tile je pe titi di bi e ti n ka iroyin yi ni oro naa si n je kayeefi fun opo awon eeyan pelu bi Aare orileede yi tele, Oloye Olusegun Obasanjo ati igbakeji alaga egbe oselu PDP tele, Oloye Bode George se pari ija, sibe ohun tawon kan n so ni pe ona lati gba ipo Aare kuro lowo Muhammadu Buhari ni Obasanjo n wa.


Gege bi iroyin to te AWIKONKO lowo losan onii, Satide lati owo akowe iroyin fun Oloye Olusegun Obasanjo, Ogbeni Kehinde Akinyemi se so, o je ko di mi mo pe Oloye Obasanjo lo loo se abewo si agba oselu naa nile e to wa n'Ikoyi, Eko.

A gbo pe ko si nnkan meji to mu ki Obasanjo pinu lati loo ki agba oloselu naa ti won ko gba ti ara won lati bii odun mewaa seyin bi ko se ti okan lara awon omo e, Dipo George to doloogbe lojo kesan an osu to koja.

A gbo pe kii se Ebora Owu nikan lo loo ki Bode George, pelu awon agba oselu lorileede yii ni won jo loo kii ku ara feraku, ti won si tun jo soro.


Obasanjo nigba to n soro so pe "Ko seni to le bi Olorun leere, nitori pe Oba aseyiowu ni, sugbon teeyan gbodo gba kamu si nnkan to ba se. Bi iru eleyi ko ba sele, ta lo mo nnkan to tun le sele.

"Mi o si nile latigba tisele naa ti sele, sugbon o wa lokan mi pe mo fe e wa, ki n le ba eyin atawon ebi yin kedun. Olorun a si te eni to ku naa si afefe rere."

Nibe lo tun ti se awon eeyan to wa nibi ikinni naa lenu nigba ti okan lara awon aburu Oloye Bode George, Alaaja Majolagbe ti won ni ko se idupe igbeyin so pe oun gba pe ko sija mo laarin Oloye Obasanjo ati Bode George.

Majolagbe so pe esu olodun pipe to ti wa laarin Oloye Olusegun Obasanjo ati egbon oun, Bode George ti gba itiju pelu bi Obasanjo se finu fedo lati wa a ki won, toun si mo pe ko tun ni si ija mo laarin awon mejeeji.

O loun mo pe asiko naa ti de pada ti Bode George yoo so Ota di ile bayii, nitori pe Olorun ti gbakoso.

Sugbon pupo ninu awon to ri bi oselu se n lo bayii, paapaa latari ikunsinu ti Oloye Obasanjo ni pelu Aare Buhari, ni won n so pe ona lati gba ipo naa kuro lowo Buhari ni Aare teleri naa n wa, eyi to mu ko lo maa pari ija pelu awon agba oselu ti won ko gba tira won lati le fimo sokan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI