ODO KO LE DI AARE ORILEEDE YI LODUN MEJO SI ASIKO YI – GBENGA ADEYINKA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, June 23, 2018

ODO KO LE DI AARE ORILEEDE YI LODUN MEJO SI ASIKO YI – GBENGA ADEYINKA


Gbajumo apanilerin nni, Ogbeni Gbenga Adeyinka ti ya opo awon odo orileede yi lenu, paapaa awon to fe e dupo Pataki-pataki lorileede yi ninu idibo odun 2019 to n bo lona lenu, latari bo se so pe ko tii to asiko fun won lati gbajoba, paapaa ipo Aare orileede Naijiria.
 
Gbenga Adeyinka (GCFR) lo soro yi losan onii, nibi eto mawon odo to nii se pelu oselu, iyen Youth Leadership Summit ti won pe akori e ni Youth Invovlment in Political Leadership and Governance: Challenges and Prospects, to waye ninu gbangan sinima ti Capricorn to wa ninu ogba Asa, iyen Cultural Centre, kuto niluu Abeokuta, lakoko to n se idanilekoo lori oselu ati agbo amuludun (Politics and Entertainment).

Agba apanilerin naa so pe ko si iye meji pea won odo ni isoro ara won, ti won won ko si le de ipo aare orileede yi lodun mejo si asiko yii, ati pe ki won tun to o le gbajoba, ironu won nipa oro olowo de gbodo yi pada patapata.

O ni iyalenu lo maa n je foun nigba toun ba n ri odo to n ki oloselu ni mesan an – mewaa, nitori ko ba a le ri owo gba lowo iru oloselu be e lai wo ipa ti iru oloselu be e ti ko lawujo ti won yan an sii.

Omo bibi ilu Abeokuta naa to ti rin irin ajo kaakiri orileede agbaye so pe se lo maa n ka noun lominu nigba toun ba n ri bi oselu won se n lo sii, ati pe orileede Naijiria nikan lo je pea won oloselu kii pe ipade tabi apero ifigagbaga, iyen public debate lati soro.

Adeyinka so pe ko ri be e lawon orileede to ku lagbaye nitori pe bi idibo ba ti n bo lona ni won yoo ti pe iru ipade yii lati so nnkan ti won fe e se fawon araalu, kawon araalu si le beere orisirisi ibeere to ba n dun won lokan ti won fe e se fun won.


O ni asiko ko re e fun odo lati gbajoba, paapaa ipo aare nitori pe awon odo bii Fela Durotoye, Omoyele Sowore atawon min ti won fe e jade dupo ni won ko lowo lowo, to si je pe ko tii si odo to setan lati fowosowopo peluu won lai gba owo lowo won.  
 


Bakan naa nigba to n soro nipa oju tawon araalu fi n wo awon to wa lagbo amuludun, iyen entertainment industry, Adeyinka so pee dun okan lo maa n je foun nigba toun ba n ri awon to wa lagbo amuludun ba n jade dupo, tawon araalu kii sii gbaruku ti won.

O ni awon bii 9ice, KOK atawon min in ni won gbaboti idibo lagbegbe ti won ti wa, to si je pe won ko wole, tawon eeyan ko dibo fun won, ati pe orin won nikan ni won feran, won ko ro awon ipa ti won le ko lawujo.

Okunrin naa ni gege bi iwe ofin orileede yi, iwe eri eko girama ni iwe eri to le mu ki oludije yege lati dupo, sugbon opo awon to wa lagbo amuludun bii Neato C, Ali Baba, D-One, AY, Seneto atawon min in to fi mo lepacious Bose to je agbejoro ni won kawe gboye ni Yunifasiti, ti won si peregede lati dupo to ba wu won laarin ilu.

Siwaju sii lo so pe ki odo to le e gbajoba, ironu won gbodo yipada patapata, ki won si gbagbe nipa oro olowo de to ba ti di oro oselu. Bee lo so pe bi awon odo ko ba sora, Buhari ti won lawon ko fe ni yoo pada wole eleekeji lodun 2019. 

Bakan naa, Ogbeni Ayo Adeshina toun naa je okan pataki lara awon to se idanilekoo tenumo on pe kawon eeyan gbagbe pe idibo yoo lo geerege lai si oro owo ninu.

O ni bi awon to fe e jade dupo ba ro pea won le jade dupo lai ni owo lowo, won kan n tan ara won je lasan ni, nitori pe ko seni to setan lati dibo fun won lai si owo.

Bee lo so pe odo oloselu ti ko ba lowo lowo pada loo wa ise ti yoo fi ri owo ti yoo lo lati fi dupo to ba wuu, o ni olowo lo n se oselu.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI