Ojuse Araalu Ni Lati Ran Ileese Eleto Aabo Lowo – Soji GanzalloSoji - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 21, 2018

Ojuse Araalu Ni Lati Ran Ileese Eleto Aabo Lowo – Soji GanzalloSoji

Ogbeni Soji Ganzallo to je oga agba egbe Fijilante tijoba ipinle Ogun, iyen Vigilante Service of Ogun state (VSO) ti so o jade sita gbangba pe ojuse awon araalu ni lati ran awon ileese eleto aabo lowo, ki won si pese awon nnkan ti yoo mu ise won rorun lati se fun won.

Soji Ganzallo
Ganzallo lo soro yi lakoko to n b’AWIKONKO soro ni ofiisi e to wa niluu Abeokuta laaro oni latari awon adojuko to n doju ko ileese won, eyi to se e se ko mu ifaseyin ba eto aabo nipinle Ogun.

Oga agba naa so pe opo awon araalu ni won gbagbo pe ojuse ijoba ni lati maa pese awon nnkan amayerorun fawon ileese to n pese eto aabo bii VSO fawon araalu, sugbon ti won ko mo pe ojuse ti won gan an lo po ninu e, nitori pe awon araalu gan an ni won n daabo bo ju.

Nigba to n kanminu lori owo tawon ileese aladani nla ati kereje-kereje, paapaa awon fi mu sise iranlowo fawon eleto aabo, o ni opo won ni ko bikita lori igbe aye awon osise eleto aabo, paapaa egbe fijilante nitori pe awon gan an ni won sunmo awon araalu ju lati je ki won ma gbe igbe aye alaafia.

Ninu oro e, o so pe “Opo adojuko lo n dojuko wa nileese yi, sugbon mo le so pe a n ri ayipada rere pelu bi awon araalu se n fowosowopo pelu wa. Tele, e maa ri pe opo awon eeyan ni won ko bikita sawon nnkan to n sele layika won, nitori ti opo won gbagbo pe bi ko ba sele si won, ko si nnkan to kan won. Sugbon nipase awon idanilekoo ati iwode ta a n se, awon eeyan naa ti n mo pe bi nnkan naa ko ba kan won, won le gbe igbese lee lori kiru nnkan bee ma baa tun sele mo. Awon min in ti e wa to je pe oju won gan an ni elomin in a se daran, ti won a si maa wo lai fi to ileese wa tabi awon olopaa leti, nitori ti won gbagbo pe ko kan won.

“Yato si eyi, awon nnkan to tun n sele ni pe nigba ti a ba mu odaran ti won wa fi ejo e sun wa, ti a ba fa won le olopaa lowo, to di pe olopaa gbe iru eni bee lo sile ejo, bi won ba pe awon to wa fejo won sun pe ki won wa a jeri nile ejo, won ko nii yoju. Elomin a ti e so pe awon ko le lo si kootu, tabi ki won so pe ko kan won mo.

“E ma je ka tan ara wa je, bi a ko ba ri eni wa a jerii nile ejo, ko si nnkan meji ti adajo yoo se ju ko da iru ejo bee nu latari bi ko se nii si eri to daju. Iru awon isoro nla ti a tun n dojuko re e, awon eeyan wa gbodo se tan lati loo jerii tako odaran nile ejo.

“Yato si eyi, oro owo tun je adojuko nla fun wa, ko si owo ti a le maa lo lati fi sise. Bi e ba wo o, opo awon moto (patrol van), okada atawon nnkan min in ti a fi n sise ni won ti denukole, ti won ko sise mo, ko si owo ta a le fi tun won se. E je ka gboriyin fun ijoba ipinle Ogun ti won ra awon moto naa fun wa, sugbon a gbodo maa tun won se latigbadegba, kii se gbogbo e nijoba le se fun wa, nitori opo awon eeyan ni iwa pe ijoba nikan lo gbodo se e, ti ko si ye ko ri bee.

“Ojuse awon ileese aladani nla ati kekere (Corporate Organization) ni lati se awon nnkan wonyi, nitori pe o gbodo pelu awon eto ilana won, iyen Corporate Social Responsibility (CSR) ti won gbodo se saarin ilu, paapaa agbegbe ti won ba wa., sugbon opo won ni won ko se e.

“Awon olowo laarin ilu gan an ko se nkankan sii lati ran eto aabo lowo, won gbagbo pe ijoba lo letoo lati se e, o lodi patapata. E wo awon Police Community Relations Committee (PCRC) ti mo je akowe (Administrative Secretary) won nipinle Ogun, pelu bi mo tun se je oga agba egben fijilante, a tun parapo lati rii pe a se iranlowo fawon olopaa.

“Lara awon nnkan ti a n se ni ka tun awon moto olopaa se, a n fun won ni taya, a n se awon nnkan to le mu aye derun fun won lati rii pe ise won n lo geerege, awon nnkan won yii ti a o rii la rii pe o je adojuko fun wa.

“Opo awon osise wa ni won ko ni nnkan ti won fi n se ese rin lati fi sise, to je pe ese ni won fi n ri lo sibi tawon eeyan ba ti daran. O ye ka pese awon nnkan to le mu ise won rorun, nitori pe iye igba ti won fi n sinmi lojumo, ko to wakati kan, tawon min in si wa ninu ile won, ti won n su oorun asundokan, ti won n gbadun lai mo pe awon kan lo n pe aabo fun won. Igba min in wa to je pe won a maa fimu finle kaakiri, tenikeni ko si nii mo.

“Iru awon osise wa yi, o ye kawon araalu maa toju won, ki won si maa gbe won gege ni, sugbon ko ri be e rara, to si seni laanu. Ijoba nikan ko le se e.”

Ganzallo nigba to n soro nipa ipo tie to aabo wa nipinle Ogun, o so pe “Lakoko mo ni lati dupe lowo ijoba ipinle Ogun fun ise takuntakun ti won n se paapaa leka eto aabo, bi e ba ranti, ki ijoba yi too de, ipo ti eto aabo wa ko see gbo seti rara, awon eeyan ko le sun ki won di oju won mejeeji, bi ki won maa ja moto gba lowo awon to nii, ipaniyan ati bee bee lo. Lesekese tijoba yi de, iyen lodun 2011 gbogbo awon nnkan yi ni won boju to, eyi gan an lo bi Fijilante, Vijilante Service of Ogun State, VSO nipinle Ogun nitori to foju han gbangba pe awon olopaa ko le da ise eto aabo se.

“Latigba ti won ti fimi sipo yi gege bi oga agba la ti bere sii sise tosan-toru, ti mo si ri daju pe a ni ibasepo to dan monran pelu awon olopaa atawon ileese eleto aabo to ku kaakiri, paapaa nipinle yi. Opo awon onise ibi, odaran la ti mu, ta a si ti gba awon irinse bii ibon atawon ohun ija oloro lowo won.

“Bi won se gba iyawo olori ile igbimo asofin ipinle Osun sile lowo awon ajinigbe ko seyin ileese wa, gbajumo olokoowo ilu Ijebu ti won ji gbe lagbegbe Ajobo lopopona Eko s’Ibadan, ileese wa naa ni, ta a si mu awon ajinigbe naa, ta a ko won lo fawon olopaa.

“E ma gbagbe pe eni to ti figba kan ri je seneto lorileede yi, Oloye Iyabo Anisulowo ti won jigbe lojo si, ileese wa yi naa lo ko ipa to joju. Opo awon ise bayii lati se lai ti menuba eyi ta n se lawon agbegbe kaakiri tawon ijoba ibile bii CDA, CDC, LCDA naa si n gboriyin fun ileese wa. Awon nnkan ta  a n se niyii, ti a o si dawo ise duro.
“Bi a tun ti se wa lasiko oselu yi, tie to idibo n sunmo etile, lagbara Olorun lose to n bo, a maa bere sii jade lati se ipolongo, ka si dawon osise wa, awon obi ati alagbato, ileese nla ati kereje pelu opo awon eeyan lekoo lori awon nnkan to ye ki won se lori oro aabo paapaa bi eto idibo se n wole de yi.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI