Gomina Abeokuta ni Amosun, kii se gomina ipinle Ogun – AD - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Thursday, June 21, 2018

Gomina Abeokuta ni Amosun, kii se gomina ipinle Ogun – AD

Egbe oselu Alliance for Democracy, AD nipinle Ogun ti fesun kan gomina Ibikunle Amosun pe kii se gomina ipinle Ogun rara, gomina ilu Abeokuta nikan ni latari awon ise akanse to n se niluu Abeokuta, lai de awon ilu to ku nipinle naa.

Agbenuso fegbe oselu naa, Komureedi Olayemi Kehinde Olowu lo gba enu alaga egbe naa, Omoba Adedayo Adeshina soro yii lasiko to n b’AWIKONKO soro lai pe yi niluu Abeokuta, tii se olu-ilu ipinle naa.

O ni ko seni ti ko mo pe oju kan soso ni Gomina Amosun n sise si, to si n paro kaakiri pe gbogbo ipinle Ogun loun n sise de, ti yoo tun maa pariwo pe ‘gbogbo e la maa se’, to si je pe etanje lasan ni.

Komureedi Olowu ni nnkan to foju han daadaa ni pe ijoba eleyameya ni Gomina Amosun n se nipinle Ogun, nitori pe gbogbo awon ise akanse to so pe oun n se, ilu Abeokuta nikan lo n se won si, ti ko si de awon ilu min in bii Ijebu, Egbado ati Remo ti won wa lara ipinle Ogun.

Ninu oro e, o so pe “Gomina wa, mo gba pe gomina Abeokuta nikan ni, kii se gomina ipinle Ogun rara. To ba je pe gomina gbogbo ipinle Ogun, ko ye ko je pe ilu Abeokuta nikan lo maa tunse, lai de awon ilu to ku bii Ijebu, Remo ati Egbado.

“Ekun meta nipinle Ogun pin si, South, West ati Central, sugbon Central ti Amosun ti wa nikan lo n sise si. E lo kaakiri ilu Abeokuta, ki e si tun lo sawon ilu ti mo daruko yi, ki e gbe won ye wo sira won, igba yen ni nnkan ti mo n so maa to ye e yin.

“Ni nnkan bi odun mefa seyin ni Gomina Amosun bere biriiji kan niluu Ijebu-Igbo, e loo wo biriiji naa lonii, ki e wo ipo to wa, ki e wa gbe e yewo sawon biriiji to bere lodun to koja, bii ti eyi to wa ni NNPC to ti pari, ati awon eyi to wa laarin Abeokuta.
“Kii se toro aheso, bi e ba gbe moto yin soju ona niluu Abeokuta, e le sun, ki e si tun maa wa moto lo lai si idaduro, sugbon e ko le dan iru e wo bi e ba de awon ilu to ku nipinle Ogun, ijamba nla ni yoo ja si.

“O see se ki oro mi dabi oro oselu leti yin, sugbon e lo si Ado-Odo Ota, Agbara, Ijebu Ode, Ijebu Igbo, e lo kaakiri Egbado, ki e wa pada wa siluu Abeokuta, igba yi gan an ni oro mi yoo too ye e yin daadaa.

“Gomina Amosun ti pari awon biriiji to bere lodun to koja, sugbon e loo wo awon akanse ise to loun n se sawon ilu to ku, ki e wo ipo ti won wa, gbogbo enu ni mo fi so o pe gomina Abeokuta ni Amosun, kii se gomina ipinle Ogun.”

Nigba to n soro nipa imurasile egbe oselu AD fun ti idibo odun 2019 to n bo lona, Komureedi Olowu so pe digbi ni egbe naa wa lorileede Naijiria, paapaa nipinle Ogun, tawon si setan lati gbajoba lowo ijoba APC to pe nijoba amunileru.

O ni bo tile je pe awon ko nigbagbo ninu Yewa lokan ti won n pariwo kaakiri, nitori pe isokan, ilosiwaju ati idagbasoke ipinle Ogun lo je won logun, eyi lo fa to fi je pe eni to ba kaju osuwon lawon fe e fa kale fun ipo gomina lodun 2019 nitori pe asiko fawon araalu lati je mudun-mudun isejoba awaarawa ti to, ta a si gbodo kuro loko eru.

Bakan naa nigba to n bu enu ate lu awoodu GCFR ti Aare Muhammadu Buhari fi ta oloogbe Moshood Abiola lore, Olowu so pe etanje ati oselu lasan ni nnkan ti Buhari se naa, ati pe lati fi wa ojurere awon araalu, paapaa awon Yoruba ni nnkan to se naa.

O tenumo on pe won ko gbe awoodu naa gba ona ofin, ti won ko si fi sinu iwe ofin (constitution) orileede yi, eyi to rorun fun ijoba to n bo lati yii danu, ki won si so pe awoodu naa ko to si Oloogbe MKO Abiola.

Lakotan, o gbawon omo Naijiria, paapaa awon omo ipinle Ogun lamonran pe ki won loo gba kaadi idibo alalope (PVC) won to je agbara won ki asiko idibo to o de, ki won le ba a lo lati fi gbe eni to wu won lokan wole lodun 2019.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI