Pasito To Ji Jenereto Soosi Gbe Dero Atimole L'Abuja - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Wednesday, June 20, 2018

Pasito To Ji Jenereto Soosi Gbe Dero Atimole L'Abuja

Kootu kan to fikale sadugbo Karmo niluu Abuja ti pase pe ki won si loo fi Pasito Emmanuel Ukaegbu pamo titi di ojo keedogbon osu yi, iyen ojo Monde to n bo lori esun ti won fi kan an pe o ji jenereto, faanu, kiboodu ati galonu gaasi ti owo gbogbo e ko din ni egberun lona ogorun (100,000) naira.


Gege b'AWIKONKO se gbo, won ni Pasito Samuel Oguche ti soosi Omega Power Ministry niluu Abuja lo loo fesun kan Emmanuel lago olopaa pe o so awon eru soosi di ti ara e.

A gbo pe se ni won ko awon eru naa fun Emmanuel ti won lomodun metadinlogbon (27) ni pe ko ba won toju e fun soosi ninu osu keji odun yi, sugbon kaka ko toju awon eru naa, se lo bere sii lo, igba to ya lo so o di tie.

Nigba to n soro naa fun adajo, agbejoro olopaa, Ifeoma Ukagha so pe gbogbo akitiyan lati gba awon eru naa pada lowo Emmanuel lo ja pabo, bo tile je pe o pada jewo pe looto ni.

Bo tile je pe Emmanuel rawo ebe pe ki won foju aanu wo oun nitori pe looto loun jebi, sibe adajo Inuwa Maidawa pase pe ki won si lo fi pamo naa titi di ojo igbejo min in.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI