AWON AKEKOO TI BOKO HARAM LE DANU KEKOO JADE L’ABEOKUTA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 31, 2018

AWON AKEKOO TI BOKO HARAM LE DANU KEKOO JADE L’ABEOKUTA


Ko din ni mokandinlogun lawon ti akekoo tawon Boko Haram le danu l’oke oya, iyen lagbegbe North orileede yi ni won ti kekoo jade nileewe awon omode ti Stephen International (Stephen International Children School) to wa niluu Abeokuta lai pe yi.

Oga agba ileewe naa, Ojise Olorun Isaac Newton lo je ko di mi mo lasiko tawon akekoo naa n sayeye ikekoo jade won lose to koja yi nileewe naa to wa lagbegbe Obantoko niluu Abeokuta.

Newton so pe nigba tawon Boko Haram le awon eeyan naa danu lasiko ti won loo gbogun ti won lawon agbegbe ti won n gbe l’oke oya naa, ilu Abeokuta ni won ko pupo ninu wa, tawon si tewo gba won nigba naa lohun.

O so pe nigba tawon tewo gba won, se lawon bere eto bi eko won yoo se te siwaju, paapaa leyin tawon se idanilekoo fun won lati mo kilaasi ti onikaluku won to si.

Nigba to n dupe lowo Olorun, oga agba naa, Isaac newton so pe bi kii ba se pe Olorun duro ti awon ni, o see se kawon ti ti ileewe naa pa, pelu awon adojuko to koju won lasiko tawon gba awon omo naa s’odo, iyen nipa gbi gbo bukata lori won.

O so pe adojuko to koju awon nigba tawon n se itoju awon omo naa fe e mi won titi, to fi mo awon oluko ileewe naa, sugbon tawon pada bori e pelu iranlowo Olorun.

Ninu oro e, o so pe “Inu wa dun nitori pe ojo ayo ati ojo idunnu ni ojo oni je fun wa, nitori pe Stephen Home ati Stephen International Children School lo n sajoyo oriire won.

“Lonii, mokandinlogun (19) ninu awon omo wa to n kekoo jade lo je pe ninu awon ti won sa asala fun emi ara won lasiko tawon Boko Haram loo da won laamu la n sayeye fun bayii, Olorun la si le fi ogo ati ola fun.

Asoju awon omoleyin Kirisiteeni nipinle Adamawa, Ogbeni Jerry Ochoechi gboriyin fun ileewe naa, paapaa awon adari e fun ise takun-takun ti won n se lati maa saanu awon ti won ko ni ipa lati lo sileewe.

Omo bibi ilu Benue naa, sugbon ti won bi sipinle Adamawa, Ochoechi so pe ajalu nla lawon n koju nipinle naa, paapaa lori wahala awon Fulani to n da won laamu lojooju mo.

Okunrin naa wa gba ijoba apapo labe Aare Muhammadu Buhari lamonran pe ko tete wa nnkan se si isoro tawon eeyan n koju l’oke oya naa, nitori pe ko yato si oro eleyemeya, to si niloo abojuto gidi.

Bee lo tun so pe looto lawon eso ologun ti fi Bibeli ati Kuraani bura pe awon yoo tubo maa daabo bo emi ati dukia awon eeyan naa nibe, sugbon kii se ibura nikan lo se se e, bi ko se pe ki won je ibura won naa wa simuse gege bi won se so.

Lara awon opo (widow) to padanu oko won lasiko ikolu awon Boko Haram naa dupe lowo awon alase ileewe naa fun iranlowo ti won se fun won, paapaa bi won ko se je ki iya je won.

Nigba to n gba enu awon opo naa soro, Arabinrin Laywat so pea won ko tile lero wi pe ireti si n be fawon, sugbon iyalenu lo je fawon nigba ti ileewe Stephen tewo gba won, ti won si n gbo bukata lori won.

PÍN-IN KÁÀKIRI