OBUN LAWON TI KO BA N FO EYIN WON LOJOOJUMO - FATUNGASE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 31, 2018

OBUN LAWON TI KO BA N FO EYIN WON LOJOOJUMO - FATUNGASE

Akowe ileewosan to n ri soro ilera ati eyin, iyen Medical and Dental Consultants Association of Nigeria (MDCAN), eka ti ileewe fasiti Olabisi Onabanjo to wa niluu Ago-Iwoye, Dokita Arabinrin Bunmi Fatungase ti gbawon omo Naijiria lamonran pe ki won maa ri daju pe won n fo eyin won mo ni gbogbo igba, lati le je ki won maa wa ni ilera pipe.


Fatungase lo soro yi nibi ayewo ilera ofe ti won se fawon osise atawon omo ile igbimo asoju-sofin ipinle Ogun, eyi to waye ninu gbongan ayeye tawon Oba, iyen Obas Complex to wa ni Oke-Mosan, Abeokuta.

O so pe, o se pataki lati maa paaro nnkan ti won fi n fo eyin, iyen buroosi (brush) losu meta-meta lati le gbogun ti awon aarun to see se ko gba enu wole, ki won si lo maa sayewo loore-koore.

Bakan naa lo tun gbawon eeyan lamonran pe ki won rii daju pe won n je awon ounje to n se ara loore, iyen protein, ki won si rora maa je iyo (salt), ki won si tun maa mu omi pupo lati gbe ilera pipe laruge.

Saaju akoko yi, ninu oro e, alaga egbe naa, Dokita Adekunle Ariba so pe o se pataki pupo lati maa dekun awon aarun nipa gbi gba awon eeyan lamonran pe ki won ye e saisan ko too di pe won yoju si Dokita.

Nigba to n gboriyin fawon osise eleto ilera naa, olori ile igbimo asoju-sofin ipinle Ogun, Onarebu Suraj Ishola Adekunbi so pe eto ti won gbe kale naa yoo se opolopo awon akopa lanfaani pupo, ti yoo si je ki won mo pataki ilera pipe.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI