IBANIDORE AYE ATIJO TI YI PADA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Saturday, July 7, 2018

IBANIDORE AYE ATIJO TI YI PADA

Lati Owo: BABATUNDE OKUNADE (OMOBA)

Mo kii eyin ololufe iroyin AWIKONKO pe e ku deede asiko yii, se alaafia le wa. Tuntun ni abala yi je ninu Iroyin Awikonko gege bi e se mo pe lojoojumo la n gberegejige sii, paapaa bi a ayipada tuntun ti se wole de pelu awon igbimo isakoso tuntun ti a ni.

Abala Agba Wa Bura ni a o ti maa yanna-naa awon asa wa ti a maa n se laye atijo, eyi ti ko si mo laye ode onii, paapaa nigba ti olaju ti e ti wa a gba gbogbo ile aye patapata.

Gbogbo ojo Abameta Satide ni abala yi yoo maa waye fun un yin lati le maa pa ironu re, ki e le maa gbadun wikendi (opin-ose) yin daadaa.

Fawon ti ko ba tii mo mi tele, emi ni Babatunde Okunade ti opo awon eeyan mo si Omoba, ilu mon on ka ni mi nitori pe mo je gbajumo sorosoro lori redio ati telifisan, bee naa ni mo tun maa n mu ode ariya dun fawon to ba pe mi.

Ohun ti mo fe e soro le lori lose yi ni 'Arugbo S'oge Ri', paapaa nipa ibanidore (relationship) aye atijo, bi okunrin se n pade obinrin, ko too di pe won gbe ara won sile. Ki asa ati ise wa (Yoruba) ma baa pare naa la se sagbekale abala yi, paapaa lati le ranti awon nnkan ti a ti se seyin.

Ni aye atijo ti okunrin ba maa fe obinrin, alarena ni won maa n lo. Alarena na le je okinrin tabi ko je obinrin, o le je ore  tabi molebi enikeni ninu okunrin tabi obinrin ti won ba nife ara won. Alarena yi ni won maa n ran si ara won nigbakugba ti won ba fe e ri ara won tabi ba ara won soro.

Alarena yi naa tun le je aburo, egbon tabi ko je eni ti won ba fokan tan ladugbo, eyi ti yoo mu ibadore naa ni itunmo si won.

O see se ki obinrin ma nife okunrin, tabi ki okunrin ma nife obinrin, sugbon bi alarena ba ti wa, oun ni yoo sise naa tawon mejeeji yoo fi gba ti ara won, bi awon mejeeji ba si ti mo oju ara won tan, dandan ni ki alarena naa yago patapata fun won, iyen ni won fi maa n so pe bi ololufe meji ba ti mo oju ara won tan, alarena a yeba kuro ni.

Sugbon saa, gbogbo e naa ko lo maa n ri bee laye atijo, paapaa julo nigba ti ede aiyede ba wa larin alarena pelu awon to n fe ara won lowo yi. O see se ko je pe adehun to wa laarin alarena ati eyikeyi ninu awon to n fe ara won yi ko lo bo se ye ko lo daadaa mo.

Bi alarena ba si ti binu, awon ololufe meji yii yoo ti seto bi won yoo tun se maa ri ara won leyin lati le maa ba ara won soro. Awon min in le sadehun pe bi won ba fe e ri ara won, ki won wa ju okuta si ori paanu ile won lati le fi se gege bi aami.

Bi okuta ba ti dun lori paanu lasiko ti won da fun ara won, oye yoo ti ye eni to wa ninu ile, yoo si jade loo ba afesona e nibi ti won ba fi ipade won si nitori pe iya ati baba awon mejeeji tabi enikeni ko tii mo si ibadore won.

Sugbon sa laye ode onii ti olaju ti wa, paapaa nigba ti foonu ti de, gbogbo e patapata lo ti yato. Afesona min in le lo sile eni to n fe, lati loo dogbon bii pe oun fe gba iwe tabi nnkan, nibe ni won yoo ti fi oju ba ara won soro.

Ati pe atejise ori foonu gan an lo po laye ti a wa bayii, won si le fe ara won fun odun meji, meta tabi ju bee lo lai je pe enikeni mo nipa e, to je pe ori foonu ni won yoo ti maa ba ara won soro.

Nibi yii ni maa a danu duro sii di ose to m bo, eyin ti e ba fe e pe mi, tabi fi atejise ranse si mi, nomba mi ti wa nibe. E tun le pade mi lori awon eto mi bii Latinu Iwe Mimo lori redio Paramount 94.5FM, Abeokuta laago mokanla koja iseju meedogun (11:15am) ni gbogbo ojo Satide, bakan naa lori eto Ijeun Agba lojo Monde ni Sweet 107.1FM, laago mejo ale (8:00pm).

E si tun le fi erongba yi ranse sibi, iyen comment to wa nisale yi. Ose to n bo la o tun pade ara wa ni abala yi. Eseun pupo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI