KI LE MAA N WO LARA OKUNRIN TO BA KO ENU IFE SII YIN KI E TOO GBA FUN? - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Friday, July 6, 2018

KI LE MAA N WO LARA OKUNRIN TO BA KO ENU IFE SII YIN KI E TOO GBA FUN?

Ibeere yi fe mi leyin, sugbon mo ni lati so o. Emi gege bi enikan, mo feran ki okunrin gaa, ko si je olotito to tun ni iwa irele bi adaba. Mo gbodo ri okunrin yen gege bi eni to ni iberu Olorun l'okan, ki iwa tutu e si je lati okan wa. Ti m ba ti ri iru awon iwa bayii, ko si nnkan to ni ki n ma gba fun un.
- Agbejoro Maryam Adenle (Eka DPP, Ibadan, Oyo)
============================================================

Ni temi o, ki n too le gba fun okunrin to ba ko enu ife si mi, maa koko wo iduro e daadaa, maa wo bo ba se ri. To ba je pe o dun un wo l'omokunrin, ti mo si rii gege bi eni ti kii fa wahala, to je bii eeyan jeje. Ma a koko wo iwa e fun bi ojo meloo kan, to ba n pe mi deede, to si n ba mi so awon oro to le yi igbesi aye eeyan pada si rere. To ba n se deede, ti mo si rii gege bi eni to ni iriri. Ko si nnkan to ni ki n ma gba fun un.
Blessing, Abeokuta
============================================================


Mo feran okunrin to beru Olorun ati pe ko je olotito eeyan, sugbon eyi to ju nibe ni pe ki okunrin je oluberu Olorun ati olotito eeyan nitori pe igbagbo mi ni wi pe ewa ara kii se ohun ti yoo maa wa lo titi. Bakan naa, bi okunrin ba ni owo lowo, ti ko ni iwa, asan ni, nitori pe iwa rere ati otito kii fi eeyan sile.
- Muhammad Morufat Osise Ijoba Ibile nipinle Oyo
============================================================


Oruko mi ni Omidan Olayiwola Titilayo Baleeqiz. Mo je onimo nipa bi a se n ko ile. Nipa ti ibeere ti e bi mi yii, emi gege bi enikan, mo feran ki okunrin ni ewa, ko si je olotito ati oluberu Olorun. Ko si tun je eni to ni igboya lati doju ko ohunkohun, bi okunrin naa ba ko enu ife si mi, dandan ni fun mi ki n gba fun.
- Omidan Olayiwola Titilayo Baleeqiz
============================================================

Ajibola Yetunde loruko mi, lati ipinle Ondo. Emi gege bi enikan, paapaa bi eyin naa se ri mi gege bi oniwa tutu, ki n too le gba fun okunrin to ba ko enu ife si mi, o gbodo jade lati idile rere nitori pe awon Yoruba maa n so pe oko buruku se e fe, ana buruku ni ko see ni. Eleekeji ni pe, o gbodo je okunrin to mo bi won se n toju obinrin, o si tun gbodo ni owo lowo, nitori pe gbogbo wa la mo pe owo ni Keke ihinrere.
- Ajibola Yetunde, Ondo
===============================================================

Ni temi o, emi o le tan ara mi je. Ki n too le gba fun okunrin to ba ko enu ife si mi, mo gbodo rii pe iru okunrin bee wa lati idile rere, ti won si lowo lowo, to si le ran ipo ti mo wa lowo. Mo tun gbodo rii gege bi okunrin to se e mu yangan lawujo, kii se pe maa fe jade, mi o ni le so pe ka jo jade, tabi ko loun fe e mu mi jade, ki n wa maa sa seyin. Mai dia ma binu, oo ni le tele mi ko s'oja, tabi kiloobu, ti m ba de, a ma maa soro, ko joo rara, ko le sise. Eleeketa ni pe, o gbodo ni iwa to daa, ki iwa awa mejeeji si ba ara wa mu. Ko ju bee lo. 
- Lade Omolade, Ondo
===========================================================

Hmmmmm! O gbodo je eni to ni iwa tutu, o gbodo je eni to n se deede, ti kii paro, to si tun maa n mu ileri tabi awon oro e se. O gbodo je eni to n ni suuru to po, ko si mo bi won se n toju obinrin. Bakan naa, o tun gbodo mo bi won se n se aponle obinrin.
Okolie Habibat, Delta
===========================================================

Ki n to le gba fun okunrin kan gege bi oko afesona, o gbodo je oniwa tutu, o gbodo je eni to mo oro o gbo daadaa, eyin to n farabale gbo oro, tii kii se oniwa jau-jau. Kii se okunrin to kan je pe o kan ma maa binu lai ni idi kan ni pato, mi o le gba fun okunrin to baa n da eero okan se. Iru okunrin bee tun gbodo le je eni to niberu Olorun. O gbodo ja fafa, ko ni imo ati oye awon nnkan daadaa, ko si mo iwe, kii se pe ti a ba fe ara wa tan, ko wa a di pe awon omo wa n gbe ise amurele (Home Work) wa sile lati ileewe, ko wa maa so pe mama ni ko loo ba. O tun gbodo je eni to le duro figagbaga laarin awon eeyan lawujo, kii se pe ko ma le baayan se po. Ko gbodo je eni to ma maa kalolo bi won ba pe e pe ko waa soro nibikan.
- Busari Oluwaseun, Ago-Iwoye
===========================================================


E seun o. Emi o, ni temi o, ki n too le gba fun okunrin gege bi oko afesona, isesi e nigba to koko pade mi lo maa je ki n mo boya maa gba fun tabi mi o nii gba fun, ati pe ti a ba n ba ore wa lo, awon iwa ni ma maa wo, bo ba se n se si mi, ti iwa ba ba ti temi mu, maa duro, ti ko ba si ba temi mu, a je pe a maa ja pa niyen. Lasiko ibadore (relationship), bi oko tabi iyawo ba n pa iro, iru ibadore bee kii pe ko too tuka. Eleekeji, nnkan ti okunrin ko ba to, ko gbodo so o, nnkan ti ko ba si le se laarin odun marun un, ko gbodo maa fi buga pe oun le se e lesekese. Igbora-eni-ye naa tun se pataki, a gbodo le gbo oro si ara wa lenu, ka si le ba ara wa gba imonran papo.
- Adurotimi Catherine Afolasade, Mapoly Abeokuta.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI