IGBADUN DE FAWON OLOLUFE IROYIN AWIKONKO: E KU OJULONA - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ


Tuesday, July 3, 2018

IGBADUN DE FAWON OLOLUFE IROYIN AWIKONKO: E KU OJULONA

IKEDE PATAKI RE E

E je ka dupe lowo ejika ti ko je ki aso ye l'orun, eyi la fi n ki eyin ololufe Iroyin Awikonko fun ife ti e n ni si wa ni gbogbo igba ati aduroti yin. Bi ko ba si eyin, ko le si awa, ka rin, ka po, yiye nii ye ni.


Lojoojumo la n gberegejige sii, ti eyin ololufe wa naa si n kan saara si wa. Kii se mi mon on se wa, sugbon ola Eledumare ni.

Kii se t'enu, kii sii se asodun tabi iro, lowolowo bayii, awon orileede bii Naijiria, Kenya, United States, United Kingdom, Indonesia, Germany, Peru, Ireland, Russia, Brazil ati Philippines ni won ti n ka Iroyin Awikonko daadaa lojoojumo, ti won si n kan saara si wa.

Lai pe yi ni awon ayipada ranpe kan de ba ileese wa, ti a si ti ni awon alabojuto tuntun ti won sese darapo mo wa, ki a tubo le gberegejige siwaju sii.

Fun un yin lati tun le maa je igbadun wa siwaju sii, igbimo idagbasoke ati isakoso Iroyin Awikonko ti jokoo, a si ti ronu lori awon nnkan ti a ro pe eyin araalu tun le maa feran lati ka, ki e si maa fi pa ironu re kuro lokan yi.

Idi ni yii ti a fi pinu lati mu awon abala min in wa, to yato gendengbe si awon iroyin ti e ti n je igbadun won lateyin wa.

Awon abala naa ni:

(i): Erongba Araalu {Public Opinion/Vox Pop}: Nibi yi ni a ti ma maa lo kaakiri lati beere nipa ojuwoye eyin araalu lori awon nnkan ti o n sele lagbegbe ati ayika yin, paapaa lorileede Naijiria.

(ii): Oro Sunukun/Binukonu {Editorial}: Eyi ni yoo maa yanna-naa awon isele to n sele kaakiri ayika ati agbegbe wa, yala lodo ijoba, araalu tabi lawujo awon oloselu. Oro amonran yoo jade lati abala yi, bee ni yoo tun si oju awon eeyan tabi ijoba si awon nnkan to n lo.

(iii): E Gba Mi: Abala yi lawon ti won ba wa ninu isoro kan tabi isoro min in yoo ti je kawon araalu mo, ti won yoo si gba won nimoran ti yoo yo won kuro ninu isoro ti won ba wa. Awon eeyan yoo fi atejise ori foonu tabi email ranse si wa.

(iv): Funmilola Animasaun: Abala yi yoo fe e da bi isokuso, sugbon ko ri bee. Ona lati le je ki eyin ololufe wa tubo maa je igbadun ni abala yi wa fun. Funmilola Animasaun je omobinrin to gbo faaji daadaa, to si maa n fe ya ara soto laarin awon to ba n ba se, paapaa awon or e. Funmilola kii se asewo tabi oloso, sugbon o feran lati maa se faaji pelu awon baba alaye to ba ja sii.

E je ka fi too yin leti pe gbogbo ojo Fraide ati Satide ni awon abala yi yoo maa waye lose-ose. Bee ni a tun n fi asiko yi si aaye anfaani sile fun awon to ba fe e fun wa ni iroyin nnkan to n sele layika ati agbegbe won pe ki won fi ranse.

Bakan naa, bo ya eyin fe e ba wa sise po nibikibi ti e ba wa, e fi itan kekere (iyen Curriculum Vitae) yin ranse si [email protected] tabi ki e ba wa soro lori WhatsApp: 07012342712.

E se pupo.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI